Mọ̀ nípa Yèyémòlú, ìyàwó Odùduwà tó di omi tí gbogbo Ooni Ile-Ife ń mu

Yeyemolu ni iyawo akọkọ ti Oduduwa fẹ gẹgẹbi itan ṣe sọ. Oduduwa, bi ẹ ko ba gbagbe, si ni o tẹ ilẹ Yoruba do.
Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ nipa rẹ, Ọọni Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, ṣalaye wi pe ọkan pataki ninu awọn alalẹ Ilẹ-Ifẹ ati ilẹ ọmọ kaarọ oo jiire ni Yeyemole jẹ.
"Oun ni Ọṣun Ọọniriṣa. Gbogbo nnkan ti Olori n ṣe fun ọba ni Yeyemolu n ṣe."
Ninu ọrọ tirẹ Oloye Oyelami Taiwo to jẹ Risa Ibilẹ ti ilu Ile-Ife ṣalaye pe Olori to ṣe abiyamọ pupọ ni Yeyemolu nigba to wa lori oke erupẹ.
Nigba to ronu titi lori ohun to le ṣe ti yoo fi jẹ manigbagbe lo fi di omi si agbala Ọọni nilu Ile Ifẹ.
Gẹgẹbi a ti gbọ, omi ti Yeyemolu parada si yii ni Ọniriṣa maa n mu to si tun fi n buwẹ.
Kabiyesi Ogunwusi ni ''Yeyemolu ni wọn n pe ni otororo omi alẹ Ife.
Gbogbo agbaye kọ lo lanfaani ati ore ọfẹ lati foju ba otororo omi alẹ Ife.''
Oloye Taiwo ṣalaye siwaju si pe ''Yeyemolu jẹ ọkan ninu awọn iyawo Oduduwa ti ko ṣabiyamọ, ṣugbọn nigba ti ọjọ n gori ọjọ ni Yeyemolu wo o pe ki ni nnkan ti oun le ṣe fun ilu Ile Ife ati fun gbogbo ọmọ Yoruba lapapọ ti wọn o fi ni gbagbe oun.
Eyi lo jẹ ko wa si ibi yii, o si lo gbogbo agbara ti Ọlọrun fun un, o si di omi si ibi.
Ṣugbọn ko to di omi yii lo ti n sọ ọ bii ẹna pẹlu ọkọ rẹ to jẹ Olori aye nigba naa pe o maa to akoko kan ti wọn maa ri iṣẹ ọwọ oun, wọn si tun maa ri aworan oun.
Amọ, ko tete ye Odua nigba naa wi pe o maa di ohun manigbagbe ni ilu Ile Ife.''
Risa Ile Ife sọ pe nigba to di ọjọ kan ni wọn wa Yeyemolu ninu aafin ti wọn ko si ri i mọ.
O ni bayii ni wọn bẹrẹ si ni wa Yeyemolu kaakiri, nigba to ya ni wọn gba oko awo lọ lati ba Onifa to jẹ Orunmila sọrọ.
Oloye Taiwo ni onifa sọ pe Yeye wa ninu aafin pe ki wọn maa wa kaakiri mọ.
Alaye lori bi Yeyemole ṣe di omi ni Aafin Ile Ife
''Ọkan ninu awọn Ọmọẹsẹ ti wọn maa n pe ni Ilari lo wa si ibi ti omi wa yii ti o si sọ pe igba wo ni omi de ibi.
O ni lati jẹ kawọn oloye ati ọba mọ, won si ni lati wa wo omi naa ki wọn to pada lọ sọdọ Orunmila pe awọn ma ri ibikan ninu aafin ti omi ti ṣẹyọ.
Bayii ni wọn tun difa ti wọn si sọ pe Yeyemolu ni. Wọn wa pe Yeyemolu lorukọ rẹ, o si dawọn lohun.
O ni oun ti sọ siwaju pe wọn maa ri iṣẹ ọwọ oun, wọn si maa ri aworan oun laipẹ, wọn si gba.
Yeyemolu di omi si ibi,'' Risa Ile Ife lo sọ bẹẹ.
Ooni Ile Ife ni ''Yeyemolu jẹ Olori akọkọ laafin, oun si ni Osun Ooni-risa, oun lo n tọju Ooni-risa, oun ni Ooni-Risa gbe gẹgẹ bi iyawo; Olofin akọkọ nigba kutu kutu owurọ.''
Risa Ile Ife ni ti nnkan ba ru eeyan loju ti iṣẹ ko lọ deedee, tawọn alawo ba sọ pe ko lọ wure nibi omi Yeyemolu, yoo ri ohun to n fẹ.
Oloye Taiwo ni adura awọn to n wa ọmọ naa n gba ti wọn ba lo omi Yeyemolu yii.
Kabiyesi Ogunwusi naa sọ pe gbogbo nnkan to ba jẹ ẹdun ọkan oun ti oun ba ti ba Yeyemolu sọ lo maa n gbọ.
''O ni bi Yeyemolu ṣe maa n jade lati bami sọrọ, ko si ojumọ aye yii ti n ko foju ba Yeyemolu.
Ti n ko ba si ni aafin ti mo ba wa lajo, o ni bi Yeyemolu ṣe maa n foju ba mi, ati pe gbogbo nnkan ti olori n ṣe fun ọba ni Yeyemolu n ṣe,'' Ooni ṣalaye.
Risa Ile Ife ni omi yii ni wọn maa n fi dana, ati pe wọn kii pọn ọn jade ninu aafin.
Oloye Taiwo ni bo tilẹ jẹ pe ko si ideri lori omi yii, o ni ko si idọti ninu rẹ rara.
Risa Ile Ife ni omi yii maa n lọọlẹ lasiko ojo, nigba ti o maa kun soke nigba ẹrun.















