Ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn kọ̀ ló n fa ìjà láàrin Israel àti Iran - Nnkan tó pilẹ̀ rẹ̀ nìyíì

Ibùdó kan tí àdó olóró bajẹ

Oríṣun àwòrán, EPA

    • Author, Busayo James-Olufade
    • Role, Senior Journalist
    • Reporting from, Lagos
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Lati bi ọsẹ kan sẹyin ni orilẹede Iran ati Israel ti n ju oriṣiriṣi ado oloro ati awọn irinṣẹ iku mii sira wọn.

Pabanbari ibẹ ni bi America ṣe da si ija naa pẹlu bo ṣe kọlu awọn ibudo mẹta ti Iran ko awọn eroja afẹfẹ aṣekupani ti wọn n pe ni nuclear weapon pa mọ si.

Lati igba ti ija naa ti bẹrẹ ni ọpọ eeyan ti n faramọ abala to ba wọn lara mu – awọn kan to jẹ Kristiẹni n faramọ Israel, ti awọn Musulumi kan si n faramọ Iran.

Idi ti eyi fi ri bẹẹ ni pe, pupọ ninu wọn gbagbọ pe, ọrọ ẹsin lo n fa wahala naa.

Amọ ṣe ọrọ ẹsin ni? Eyi ko ri bẹẹ rara, koda, ija laarin orilẹede Israel ati Iran, to fi mọ Palestine, ko ni ohunkohun lati ṣe pẹlu ẹsin.

Mo mọ pe ibeere to n ja lọkan yin bayii ni pe, ki wa lo n fa ija naa?

Ẹ ma a ba wa kalọ.

Ibùdó tí àdó olóró ba

Lati ọdun 1979 ni ko ti si ajọṣepọ tabi ibadọrẹ kankan laarin Iran ati Israel.

Kii ṣe pe wọn ko ṣe ọrẹ ri, alajọṣepọ ni wọn ṣaaju ogun ti wọn pe ni Cold War.

Lasiko ogun naa ni nnkan bẹrẹ si ni i bajẹ, amọ o bajẹ patapata lẹyin ti Iran jijagbara lasiko Iran Revolution, to si n 'ja' lati igba ti ogun Gulf War ti pari lọdun 1991.

Ijọba to wa lode ni Iran ko tẹwọgba Israel gẹgẹ bi orilẹede, to si ti n pe fun iparun rẹ.

Palestine lo n ri gẹgẹ bi ijọba to ni aṣẹ lori awọn agbegbe kan.

Israel paapaa n wo Iran gẹgẹ bi ewu ti yoo da alaafia to wa ni Middle East ru, to si ti n kọlu awọn ibudo nnkan amuṣagbara Iran fun igba pipẹ.

Ibùdó kan tí àdó olóró bá

Ki lo de ti Israel kọlu Iran?

Oun ti awọn alaṣẹ orilẹede Israel n sọ ni pe ko si nnkan meji ti awọn ni lati ṣe ju pe ki wọn o ju ado oloro si Iran.

Igbagbọ wọn ni pe lati bi oṣu diẹ si asiko yii ni Iran ti n tẹpẹlẹ mọ akitiyan rẹ lati ṣe awọn eroja afẹfẹ oloro, ti wọn n pe ni nuclear weapon.

Gbogbo ijiroro lati mu ki Iran dawọ duro si ni ko so eso rere.

Wọn ni awọn ri igbesẹ yii gẹgẹ bi idunkooko mọ ni lati ọdọ Iran, pẹlu alaye pe ti Iran ba fi ni awọn irinṣẹ iku naa, dandan ni yoo lo o nitori pe o ti leri sẹyin lati pa orilẹede Israel run.

Bawo ni ibaṣepọ ṣe bẹrẹ laarin Israel ati Iran ode oni?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Labẹ iṣakoso Pahlavi to ṣe ijọba lati ọdun 1952 si 1979, ibaṣepọ to dan mọran lo wa laarin Iran ati Israel.

Ko da, Iran ni orilẹede ẹlẹsin Islam keji to tẹwọgba Israel lẹyin ti wọn da a silẹ lọdun 1948.

Lati bi ọdun kan ni Iran ti darapọ mọ awọn orilẹede to n bu ẹnu atẹ lu bi Israel ṣe n kọlu Gaza.

Eyi si wa ni ibamu pẹlu iha atako ti Iran kọ si awọn iṣeṣi Israel si awọn orilẹede ilẹ okeere.

Ija to n waye laarin Israel ati Iran bẹrẹ lati biba ara ẹni ṣe orogun ni ẹkun ti wọn wa.

Pupọ ninu awọn nnkan to wa nidi ija naa si bẹrẹ nigba idasilẹ orilẹede Juu lọdun 1948.

Bo tilẹ jẹ pe awọn onkọtan kan gbagbọ pe orisun ija naa ti wa tipẹ, idasilẹ orilẹede Israel lo mu ki nnkan buru si i.

Ara erongba lati pin orilẹede Palestine ti Britain n dari si ọna meji – Ilẹ Juu ati Arab – lo bi idasilẹ Israel.

Awọn eeyan Juu to kere ju ninu ẹya mejeeji, ni wọn ṣe ileri ida 56% ilẹ naa fun, ti awọn naa si gba.

Amọ awọn Arab tako o.

Lati igba naa si ni wahala ti bẹrẹ. gbogbo ireti Arab lati da Israel duro, lo ja si ofo.

Ọpọlọpọ oṣu ni wọn fi ja, eyi to mu ki Israel gba lara ilẹ Palestine, ti wọn si ṣi bii ida meji awọn eniyan Arab nidi kuro nilẹ wọn.

Ogun naa ni wọn n pe ni Nakbah.

Lootọ ti ipẹtu saawọ kan waye, amọ ọpọ nnkan to n fa ija ni wọn ko yanju.

Ọpọlọpọ ọdun to tẹle si ni wọn fi n ja, paapaa lọdun 1956, 1967 ati 1973.

Ogun ọjọ mẹfa ti wọn ja lọdun 1967 gba ilẹ yooku lọwọ Arab.

Lati East Jerusalem, the West Bank, ati agbegbe Gaza Strip, eyi si tubọ mu ki wahala to wa nilẹ buru si.

Diẹdiẹ ni Iran di alagbara ni ẹkun Middle East, to si bẹrẹ si ni i ṣe atilẹyin fun awọn ikọ ajijagbara ni Palestine bii Hamas.

Atilẹyin yii ni awọn onwoye ṣapejuwe gẹgẹ bi ara ọna ti Iran fẹ fi gbogun ti bi Israel ati America ṣe ko ẹkun naa ni papamọra.

Ibùdó kan tí àdó olóró bá

Bawo ni nnkan ṣe bajẹ to bayii?

Olootu ijọba Israel, Benjamin Netanyahu sọ ni ọjọ Ẹti to kọja pe, awọn ikọlu naa jẹ "iṣẹ ologun to fẹ ikọlu ibudo nuclear ti Iran".

O sọ pe ikọlu yoo "tẹsiwaju fun ọpọlọpọ ọjọ bi o ṣe gba lati yọ itankale Iran kuro".

Oṣiṣẹ ologun Israeli kan sọ fun BBC Iran ni awọn ohun elo iparun to lati ṣẹda awọn bombu iparun "laarin ọjọ repete".

Iran ti sọ pe awọn ko ṣẹda awọn ohun ija yii fun wahala ṣugbọn fun alaafia.

Awọn ikọlu naa bẹrẹ lẹyin to han pe ijiroro US lori eto iparun Iran, eyi ti o bẹrẹ ni oṣu Kẹrin, dabi ẹni pe o ti dawọ duro.

Aarẹ Donald Trump ti ni reti lati ṣe adehun kan lati da Tehran duro ninu siṣẹda ohun ija iparun kan, ṣugbọn ijiroro naa ko waye.

Ni ọdun to kọja, Iran ati Israeli fi ọpọ ado oloro kọlu ara wọn ni oṣu Kẹrin ati oṣu Kẹwaa .