Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àdéhùn jógun-ó-mí tí Trump kéde fún Israel àti Iran

Oríṣun àwòrán, Reuters
Aarẹ orilẹede America, Donald Trump, ti kede pe Israel ati Iran ti gba lati jẹ ki ogun o sinmi laarin wọn.
Owurọ kutu ọjọ Isẹgun ni Trump kede eyi, to si kilọ fun orilẹede mejeeji lati ma tapa si adehun naa.
Lẹyin wakati diẹ ti Trump kede, ni Israel naa fidirẹ mulẹ, ti wọn si ni ti Iran ba tasẹ agẹrẹ, awọn ko ni I tẹti lati gbẹsan.
Ṣaaju ni Iran ti sọ pe awọn yoo dawọ ikọlu duro, ti Israel naa ba gbe iru igbesẹ bẹẹ.
Adehun yii waye lẹyin ti Iran ju ado oloro si awọn ibudo kan to jẹ ti America, nibi to jẹ ibudo awọn ọmọ ogun oju ofurufu ilẹ America ni orilẹede Qatar.
Amọ ṣa, awọn alaṣẹ ni Qatar sọ pe gbogbo awọn ado oloro naa ni awọn re danu.
Ileeṣẹ iroyin Iran, IRINN sọ pe, Trump bẹbẹ fun adehun dida wọ ogun duro lẹyin ti awọn ṣe ikọlu.
Bakan naa ni wọn gbe oriyin fun awọn ọmọ ogun Iran, Iran Islamic Revolutionary Guard Council (IRGC), fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe.
Wo bi adehun jogun o mi naa ṣe lọ
Ni oru ana ni Donald Trump kede pe, Iran ati Israel ti gba lati jẹ ki ogun o sinmi, nigba ti yoo si fi aago mẹfa idaji, o sọ pe ogun ti tan laarin orilẹede mejeeji.
Aago meje kọja iṣẹju mẹwaa owurọ ni Israel fi ikede sita pe, awọn ti gba lati dawọ ogun duro.
Ṣaaju ki adehun naa to bẹrẹ iṣẹ, ni orilẹede mejeeji, ti kọju ija sira wọn loru-mọju. Ko si ti i foju han ni pato, iye eeyan to ku tabi farapa ni Iran.
Amọ nnkan to han ni pe, oru ana lo ti i buru ju ni Tehran, gẹgẹ bi akọroyin BBC ṣe sọ.
Israel sọ pe ko din ni eeyan mẹrin to ku, ti awọn mejilelogun si farapa ni ilu Beersheba.
Ijọba Israel sọ pe awọn gba adehun naa lẹyin ti "awọn ti mu ipinnu wọn lori ikọlu si Iran ṣẹ".
Bakan naa ni wọn sọ pe ipalara ati iparun nla ni awọn mu ba awọn olori ogun Iran, ti awọn si tun ba ọpọlọpọ awọn nnkan amuṣagbara ijọba orilẹede naa jẹ.
Israel fẹsun titapa si adehun jogun-o-mi kan Iran, pinnu lati fesi nla pada
Minisita fun aabo lorilẹede Israel, Israel Katz fi atẹjade sita bayii lati fẹsun kan Iran pe, wọn ti tapa si adehun jogun-o-mi to n lọ lọwọ, to si palaṣẹ fun ileeṣẹ ologun Israel lati fesi pada, eyi ti yoo mi ilu Tehran.
Ẹwẹ, orilẹede Iran ti fesi pada pe awọn ko tapa si adehun naa, ti awọn ko si ju ado oloro kankan si Israel lasiko adehun jogun-o-mi.
Ko pẹ si ikede nipa pe ado oloro ti Iran ju si Israel, Minisita fun eto isuna lorilẹede Israel kede loju opo ayeluja rẹ pe, Tehran, iyẹn olu-ilu Iran, yoo mi titi.
"Tehran yoo mi titi," Bezalel Smotrich, ọkan lara amugbalẹgbẹ olootu ijọba Israel Benjamin Netanyahu, sọ lori opo X.
Bakan naa ni Ọga ologun Iran, Abdolrahim Mousavi ni ko si nnkan to jọ mọ pe Iran ju ado oloro si Israel.
Ileeṣẹ ologun Israel naa jẹ ko di mimọ awọn naa ṣetan lati fesi nla pada ti orilẹede Israel ba pinnu lati kọlu Iran.












