Ṣé lóòótọ́ ni ìjọba Kwara ń fòfin de àwọn oníbárà, gbé wọn lọ ilé-ẹjọ?

Oríṣun àwòrán, Ministry of Social Development
Ijọba ipinlẹ Kwara ti bẹrẹ fi fofin gbe awọn agbabara ni ilu Ilorin ti o jẹ olu fun ipinlẹ Kwara.
Igbesẹ yi ti bẹrẹ ni bi ọjọ diẹ sẹyin bi wọn si se n se gbe awọn agbabara yi ni wọn n gbe wọn re ile-ẹjọ alagbeka, ti wọn si n sedajọ wọn lẹsẹkẹsẹ.
Bi awọn kan ṣe n ri ẹwọn he naa ni idajọ awọn kan jẹ isẹ ilu (Community Service)
Ninu iroyin kan lori ayelujara lati rii ka pe, komisanna fun eto idagbasoke, (Social Development) fun ipinlẹ ọhun, Hajia Mariam Nnafatima-Imam, lo saaju awọn ẹsọ ijọba lati le gbogbo awọn agbabara naa.
Koda, Iroyin ọhun gbee pe, o ti to agbabara mẹrindinlaadọrin (66) ati ọkunrin ati obinrin to fi mọ awọn ọmọde ni wọn ti fofin gbe latigba ti ijọba ti bẹrẹ igbesẹ ọhun.
Ọrọ yi lo n fa awuyewuye ati ibeere laarin ilu wi pe, njẹ awọn agbabara naa jẹ araalu ati pe ṣe wọn ni ẹtọ abi wọn ko ni?
Ìjọba Kwara ṣàlàyé ìdí tó fi ń fòfin gbé àwọn agbabárà
Lọjọ isẹgun, ọjọ kinni osu keje, BBC Yoruba kan si ẹka to n ri seto idagbasoke lati mọ idi pato tan fi n ko awọn agbabara kuro nilẹ, ati lati mọ boya igbesẹ naa tẹ ẹtọ wọn loju mọlẹ abi ko tẹ ẹ.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu akọwe agba (Permanent Secretary) ẹka naa, alagba Ayanwale Peter Kayode sọ pe araalu ni awọn agbabara, awọn naa si ni ẹtọ kii si se pe, ijọba n tẹ ẹtọ wọn mọlẹ.
"Idi pataki ti ijọba fi ko wọn kuro loju popo pọ,
"Lara rẹ ni pe, ti a ba wo awọn agbegbe kan bi Geri-Alimi, Airport, Post Office, Garrage Offa, Tanke ati awọn ibo mii, a o ri pe awọn agbegbe yi jẹ ibi ti ijọba n boju to, ti wọn si n nawo biribiri le.
"Sugbọn awọn agbabara wọn yii, ti a ba wo abẹ afara Tankẹ, wọn ti sọ ibẹ di ile, ni ọpọ igba, igbẹ ni wọn n fi ba ibẹ jẹ. Wọn tun sọ ibẹ di ibi ti sun kẹrẹ fa kẹrẹ ọkọ ati ẹsẹ ti n sẹlẹ lori pe wọn tọrọ bara, awọn miran a jana mọ mọto lẹnu,
"Idi miran ni pe, ọpọ wọn ni wọn n se agbodegba fun awọn ole, ti wọn n ko ọpọlọpọ nnkan. ni ọdun to kọja, a mu ninu wọn, ọpọ la ba awọn ohun oloro bi ọbẹ, ada, orisirisi oogun lọwọ wọn.
"Ki ni agbabara n wa pẹlu ọbẹ, ki lo n fi ada ṣe? Ọpọlọpọ awọn nnkan wọn yẹ la ko lọ agọ ọlọpaa gẹgẹ bi ẹri.
"Iyẹ nikan kọ, ti a ba de oju popo wa, ni ọpọ igba ni ẹẹru ma n ba eniyan pẹlu bi awọn agbabara yi ṣe n mura.
Òpọ̀ àwọn agbabárà yìí ni wón ń ṣe agbódegbà fáwọn olè - Akọ̀wé àgbà

Oríṣun àwòrán, Ministry of Social Development
"Idi miran ni pe, ọpọ wọn ni wọn n se agbodegba fun awọn ole, ti wọn n ko ọpọlọpọ nnkan. ni ọdun to kọja, a mu ninu wọn, ọpọ la ba awọn ohun oloro bi ọbẹ, ada, orisirisi oogun lọwọ wọn.
"Ki ni agbabara n wa pẹlu ọbẹ, ki lo n fi ada ṣe? Ọpọlọpọ awọn nnkan wọn yẹ la ko lọ agọ ọlọpaa gẹgẹ bi ẹri.
"A ti ṣe ipade pẹlu awọn olori wọn ni ọpọ igba ti a si ti jẹ kan mọ ipinnu ijọba, eleyi ti wọn fara mọ.
"A ni wọn le duro ni awọn agbegbe ọja ọba si Gambari, titi de Ipata, a si fọkan wọn balẹ pe, a o maa kan si wọn pẹlu awọn ohun agbaye gbadun ti ijọba ba n se, a si n se bẹẹ gẹgẹ.
"A tun n se eyi nitori awọn to lapa, to lẹsẹ, ti nkankan o se, ijọba ni kan lọ wasẹse tabi ko lọ kọsẹ, tabi kan lọ dako, ijọba ti pese ibi ẹkọsẹ imọ nipa ẹrọ bẹẹ si ni wọn pese awọn ohun idako lọfẹ fawọn to ba fẹ dako.
"Fun idi eyi, emi o ri awawi fun awọn to lapa lẹsẹ lati maa tọrọ bára.
"Awọn ti a n mu ti a si n wọ lọ ile-ẹjọ jẹ awọn ti a ti mu lọpọlọpọ igba ti wọn si n tapa sofin.
"Ijiya wọn nile ẹjọ si da lori bi ẹsẹ wọn ba se tobi to, ileẹjọ n ran awọn mii lẹwọn, awọn mii si jẹ isẹ ilu (Community Service) lasan.
Ohun ti ijọba n sọ ni pe, awọn o fẹ agbabara ni awọn agbegbe ti mo ti darukọ saaju, sugbọn ko si ẹsẹ ti wọn ba wa ni awọn ibi ti ijọba ni wọn le duro.















