Ẹ wo bí ìgbẹ́jọ́ àwọn afurasí tó ṣagbátẹrù CBEX ṣe lọ nílé ẹ̀jọ́ lónìí

Oríṣun àwòrán, Others
Ileẹjọ giga apapọ niluu Abuja ti yi ẹbẹ eeyan mẹta to ṣagbatẹru eto sogun-dogoji CBEX to gbe owo ọpọ ọmọ Naijiria lọ lati gba beeli ni atimọle EFCC, danu.
Ko din ni $1bn tawọn ọmọ Naijiria padanu sinu eto sogun-dogoji CBEX.
Ṣaaju ni awọn agbẹjọro eeyan mẹta naa ti bẹ Onidajọ Emeka Nwite ti ile ẹjọ giga ilu Abuja lati fun awọn onibaara awọn ni beeli ni ahamọ EFCC tniori wọn ti pẹ nibẹ.
Ajọ EFCC sọ fun ile ẹjọ wi pe awọn afurasi mẹta naa lo orukọ ileeṣẹ kan ti wọn n pe ni ST Technologies lati polowo CBEX fawọn ọmọ Naijiria.
EFCC sọ pe lẹyin naa lọpọ ọmọ Naijiria bẹrẹ si ni dokowo pẹlu wọn.
Bakan naa ni ajọ naa tun ṣalaye pe, awọn ọmọ Naijiria to bọ sọwọ fi owo ti ko din $1bn dokowo sori CBEX.
"Lẹyin ti awọn eeyan fi owo gọbọi dokowo tan ni oju opo CBEX ko ṣi mọ fawọn eeyan lati le gba owo wọn pada.
Nigba naa ni o too han si onikaluku pe, jibiti ni eto CBEX ọhun."
Lẹyin ti adajọ Nwite ṣe agbeyẹwo awijare ajọ EFCC ni o sọ pe otitọ lọrọ ti ajọ naa sọ.
Adajọ Nwite ko beṣu bẹgba lati gba si EFCC lẹnu wi pe kawọn eeyan mẹta to ṣagbatẹru eto CBEX ni Naijiria si wa latimọle EFCC sibẹ.
Wo bí o kò ṣe ní í lùgbàdì CBEX lẹ́ẹ̀kan sí i
Oṣu Kẹfa ni iroyin tun jade pe, ileeṣẹ olokoowo ori ayelujara Cbex tun ti pada de, ti wọn si n wa awọn onibaara tuntun, wọn si tun fẹ ki awọn to ti wa nibẹ tẹlẹ mu owo si i wa.
Ẹka Federal Bureau of Investigation, (FBI), gba awọn eeyan nimọran lati ma ṣe sare tun kowo si CBEX.
O ni ki wọn ṣe iwadii wọn daadaa ki wọn too rọ lu u, nitori awọn ileeṣẹ sọ-ogun-di-ogoji bayii maa n wa onibaara tuntun ti wọn yoo fi owo wọn sanwo fun awọn mi-in ni.
Bí o ṣe lè gba ara à rẹ lọ́wọ́ okòwò jìbìtì - SEC
Bakan naa ni ileeṣẹ to n ri si paṣipaarọ ati idunaa-dura ni Naijiria (Securities and Exchange Commission), kilọ fun awọn eeyan lori awọn okoowo onijibiti.
Wọnyi ni awọn nnkan ti wọn ni ki ẹ sa fun:
Ibi yoowu to o ba ti n fi owo gba owo.
Ibi ti wọn ba ti n fi nọmba ranṣẹ si foonu rẹ, ti wọn n sọ pe ki o da nọmba naa pada fawọn.
Ibi ti wọn ba ti ṣeleri ọrọ̀ ojiji fun ọ lai daamu rara.
Awọn okoowo to n ṣeleri owo to ṣoro lati gbagbọ pe wọn yoo fun ọ.
Ṣọra fun ibi ti wọn ti n kan ọ loju lati tete ba awọn da owo pọ lai ro o jinlẹ ki o too kowo kalẹ.
Ṣọra fun ibi ti wọn ti fẹẹ mọ ohun gbogbo nipa rẹ nitori okowo to da yin pọ.
Ṣọra fun ibi ti wọn ti ni awọn yoo sọ ọ di milọnia labẹnu ti ẹnikan ko ni i mọ si i.
Awọn ti wọn yoo ni ki o waa gba ẹbun, ṣugbọn ti wọn yoo kọkọ ni ki o mu owo wa na.
Ṣọra nibi ti wọn ba ti ni o gbọdọ ko awọn eeyan wa lati fi orukọ silẹ na ki o too le gba ẹbun tirẹ.
Awọn ti wọn yoo ni ki o waa gba ogún mọlẹbi ti o ko mọ nipa rẹ.
Ṣọra fawọn ti wọn ni dandan ni ki o jere, pe o da awọn loju.
Ṣọra fawọn to n gba oju opo crypto nikan sanwo.
Ṣọra fun oju opo ti ko jọ tootọ biwọ naa ba n wo o.
Ṣọra bi ẹni to n gba owo lọwọ ọ rẹ ko ba fun ọ ni ẹri owo ti o n san wọle.
Bi wọn ba n sọ fun ọ pe ki o ma sọ nipa okowo naa fun ẹnikan kan.
Ṣọra fun akọṣẹmọṣẹ to ni ki o ma fi ofin kun ibi ti o n kowo si.
Mọ ibi ti o fẹẹ ko owo rẹ si daadaa.
Mọ ibi ti o fẹẹ ko owo rẹ si, tinu-tẹyin.
Ṣọra bi wọn ko ba le ṣalaye okowo to fẹẹ fun o ni èrè gọbọi.
Ṣe iwadi boya ọja tabi iṣẹ ti wọn n ṣe nibi ti o fẹẹ ko owo rẹ si ki i ṣe ayederu.
Ṣe iwadii boya èrè ti wọn n jẹ n fi gbogbo igba wọle.
Okowo ti wọn ko ba ti le ṣalaye fun ọ ko ye ọ yekeyeke, ma ko owo rẹ le e lori.












