Afurasí aláboyún akẹ́kọ̀ọ́bìnrin fásítì UNIPORT dáná sun ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀, ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

Aworan yara ti ijamba ina ti ṣẹlẹ

Oríṣun àwòrán, BarristerStreet/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ijamba ina to gbẹmi ọdọkunrin kan, Sunny Amadi lagbegbe Choba nipinlẹ Rivers.

Iyalẹnu lo jẹ fun ọpọ eeyan nigba ti wọn gbọ pe Amadi ẹni ọdun mọkandinlọgbọn ti ku lẹyin ti afurasi ọrẹbinrin rẹ sọ ina si i lara.

Ibatan ọrẹbinrin naa sọ fun BBC Pidgin pe iṣẹlẹ ọhun waye lopopona Ogbogoro ni Choba lagbegbe ọgba ile ẹkọ fasiti UNIPORT.

Ohun ti a gbọ ni pe ina jo ọrẹbinrin naa nibi iṣẹlẹ ọhun.

Gẹgẹ bii nnkan ti a gbọ, ọmọbinrin naa jade lọjọ ti iṣẹlẹ ọhun sẹlẹ lati lọ ra nnkan, nigba ti o pada sile ni o ri pe ina abẹla wa ni titan silẹ.

''O ya a lẹnu tori o loun o tan abẹla ki oun to jade bo tilẹ jẹ pe ko si ina ẹlẹtiriki lasiko naa.

Amọ, nigba to wọle pada ni o ba ọrẹkunrin rẹ tẹlẹ ninu ile pẹlu epo bẹntiroolu ninu galọọnu.''

Ibatan ọmọbinrin naa sọ pe ọrẹkunrin yii ati ọmọbinrin naa ti pinya tẹlẹ, o si ti sọ fun ọmọkunrin naa wi pe ki o ma pe oun mọ, ki o si ma sun mọ ibi toun ba wa mọ bakan naa.

Amọ, ọrẹkunrin naa ko gbọ, ni ṣe lo n bẹ ọmọbinrin yii.

''Bayii ni wọn bẹrẹ si ni tahun sira wọn, nigba ti ọmọbinrin naa fẹ jade ni epo to wa ninu galọọnu yi danu ti o si gbana lati ibi ina abẹla ti wọn tan silẹ.

Bayii ni ina ọhun ṣe bo awọn mejeeji, o gbiyanju lati sa kuro ninu yara ṣugbọn ina ti n jo ara rẹ.

Alabagbe rẹ kan lo pe mi lori foonu wi pe ki n wa wo nnkan to ṣẹlẹ.

Lẹyin naa ni mo sare wa lati abule ti a si gbe awọn mejeeji lọ si ile iwosan.

Amọ, o ṣeni laanu wi pe ọmọkunrin naa padanu ẹmi rẹ tori ina ti jo o lara gan an.

Bakan naa ni ọrẹbinrin rẹ wa ni ẹsẹ kan aye ẹsẹ kan ọrun tori ina ti jo oun naa lara gan an,'' ibatan ọrẹbinrin naa lo sọ bẹẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori ohun to ṣokunfa ijamba ina

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers, SP Grace Iringe-Koko, ti fidi rẹ mulẹ pe nile iwosan ni ọrẹkunrin naa ku si, nigba ti ọrẹbinrin rẹ si n gba itọju lọwọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ko tii mọ ohun to ṣokunfa ijamba ina ọhun, ṣugbọn awọn kan n sọ pe akẹkọọbinrin naa to wa ni ọdun kẹta lẹnu ẹkọ rẹ ni fasiti UNIPORT lo dana si ọrẹkunrin rẹ lara.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii si n lọ lori iṣẹlẹ naa, nigba ti wọn si n gbadura pe ki ọmọbinrin yii gbadun ki o le ṣalaye nnkan to ṣẹlẹ gan an tori o fara ṣeṣe pupọ nibi ijamba ina ọhun.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni akẹkọọbinrin yii tun wa ninu oyun fun ọrẹkunrin rẹ to ti di oloogbe.

''Ileeṣẹ ọlọpaa ti ri akẹkọọbinrin naa to loyun, nibi to ti n gba itọju nile iwosan.

Ọjọ ti lọ lori oyun ọmọbinrin naa, ko le ṣalaye nnkan to ṣẹlẹ bayii nitori bi ara ṣe ri.

Amọ, yoo ṣalaye fun wa nnkan to ṣẹlẹ ti ara rẹ ba ti ya,'' agbẹnusọ ọlọpaa ṣalaye.