Ẹ yọ orúkọ mi kúrò lára àwọn afurasí tí wọ́n ń wá torí mi kìí ṣe ọ̀daràn - Sunday Igboho

Aworan Sunday Igboho

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ilumọọka ajijagbara to n pe fun idasilẹ orilẹede iran Yoruba, Sunday Adeyemo, ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ti rọ ijọba apapọ lati yọ orukọ rẹ kuro lara awọn afurasi ti wọn n wa.

Igboho sọrọ yii lasiko to ṣabẹwo si Olugbon ti Orile Igbon, Ọba Francis Alao, ni aafin rẹ lọjọ Iṣẹgun ọjọ kejilelogun oṣu Keje yii.

Owo Baba Dami lo anfaani abẹwo rẹ lati rọ kabiesi naa lati ṣe iranwọ fun un lori ati di ominira rẹ pada ni Naijiria.

Igboho ni ''inu mi o dun wi pe n ko ni ominira lati rin nilẹ baba mi.

Mo fẹ ki ijọba apapọ yọ orukọ mi kuro lara awọn afurasi ti wọn n wa tori mi kii ṣe ọdaran.

Ọpọ eeyan lo n dunkoko mọ mi lati pa mi, mi o le sun daadaa nile mi mọ.

Laipẹ yii ti mo lọ si olu ileeṣẹ orilẹede Naijiria ni Germany lati gba iwe irinna mi ni wọn sọ fun mi pe ijọba apapọ ti kọ lẹta sawọn pe mo wa lara awọn afurasi ti wọn n wa.

Ohun ti mo fẹ ni pe mo fẹ ni ominira gẹgẹ bii ọmọ Naijiria.''

Bakan naa ni Igboho tun sọ pe eto abo to mẹhẹ nilẹ Yoruba n fẹ amojuto ni kiakia.

Owo baba Dami ko ṣai dupẹ lọwọ kabiyesi Olugbọn fun atilẹyin ori-ade naa fun un lati ẹyin wa.

Ọgbẹni Adeyemo ni ''Ọba Olugbọn wa lara awọn awọn ọba alaye to duro ti mi, mo mọ riri nnkan ti kabiyesi ṣe fun mi.''

Nigba to n sọrọ lori eto abo to mẹhẹ lapa iwọ oorun guusu Naijiria to jẹ ilẹ Yoruba, Igboho rọ ijọba apapọ lati yan awọn ẹṣọ eleto abo to to gbangba sun lọyẹ lati pese abo to peye nilẹ Yoruba.

O rọ ijọba lati yan awọn to le ṣiṣẹ naa sipo tawọn to ba wa nibẹ ko ba le ṣe e daadaa.

Igboho ni oun ṣetan lati ṣe atilẹyin fawọn ẹṣo eleto abo ti wọn ba gbe iṣẹ naa fun.

Sunday Igboho kii ṣe ọdaran - Olugbon

Ẹwẹ, Kabiyesi Olugbọn ninu ọrọ rẹ ṣapujuwe Ighoho gẹgẹ ẹni to fẹran ilu rẹ denu ti o si kopa ninu igbiyanju lati jẹ ki iran Yoruba de ipo aarẹ Naijiria pada.

Olugbọn fi da Igboho loju wi pe oun ṣetan lati ran an lọwọ, koda, ori-ade naa tun sẹleri lati ba Alaafin sọrọ lori ọrọ ọhun.

''Sunday Igboho kii ṣe ọdaran, o kopa ninu igbiyanju lati ri pe ọmọ Yoruba de ipo aarẹ pada.

Mo fi asiko yii rọ Aarẹ Bola Tinubu lati fori jin Sunday Igboho ki o le wa ni ominira pada.

Bakan naa ni mo tun rọ gbogbo awọn gomina ilẹ Yoruba lati fohun ṣọkan ki wọn si ba aarẹ sọrọ lori ati fun Igboho ni ominira rẹ pada.

Eyi ti Igboho ṣe niluu oyinbo ti to, a nilo rẹ nilẹ Yoruba bayii,'' Olugbọn lo sọ bẹẹ.

Olugbọn ko ṣai rọ ijọba apapọ lati fi Igboho ṣe olori awọn ẹṣọ eleto abo nilẹ Yoruba nitori iriri rẹ.

Ọba Alao ni oun yoo fi imọran naa ranṣẹ sawọn gomina ki wọn le sọ fun Aarẹ Tinubu.