Ijọba Ghana bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí àwọn nńkan ìja ogun tó pòórá níléeṣẹ́ ológun wọn

Aworan awọn nnkan ija ogun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Minisita eto abo lorilẹede Ghana, Edward Omane Boamah, ti paṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ lori awọn nnkan ija ogun orilẹede naa to 'poora, tabi sọnu' lọdọ awọn ologun ilẹ wọn.

Ṣaaju idibo to waye loṣu Kejila ọdun 2024 ni awọn nnkan ija naa deede di awati.

Minisita eto aabo Ghana fidi ẹ mulẹ, pe ẹka to n ri si aabo ni lorilẹede yii ko le sọ pato ibi ti awọn irinṣẹ aabo ilu naa wọlẹ si.

" Ileeṣẹ ologun orilẹede Ghana ti fi iṣẹlẹ yii to ẹka aabo apapọ leti lati ṣe ayẹwo rẹ, nitori awọn ni wọn gba awọn nnkan ija ogun naa tẹlẹ."

Kí ni Ààrẹ Ghana, John Mahama, sọ?

Aworan awọn nnkan ija ogun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Keji ọdun 2025 yii ni aarẹ Ghana, John Mahama, kọkọ sọrọ nipa awọn nnkan ija yii.

O ni o ṣee ṣe ki wọn ti bọ sọwọ ọpọ eeyan ti ko yẹ.

"Mo fẹẹ fi da yin loju pe a ko fi ọwọ yẹpẹrẹ mu ijọba awaarawa, paapaa pẹlu ọrọ nnkan ija awọn ologun to ti bọ sọwọ awọn ti ko yẹ ninu ijọba to kuro lori aleefa."

" Idaamu gbaa ni awọn nnkan ija to sọnu yii n ko ba eto aabo awọn ọmọ Ghana pata.

"O le mu ki rogbodiyan to n ṣẹlẹ lawọn apa kan orilẹede yii le si i, o si le fa idigunjale. "

Ṣugbọn iyalẹnu lo wa jẹ pe lati oṣu karun-un sẹyin ti Aarẹ Mahama ti sọrọ yii, wọn ko ti ri awọn nnkan ija naa.

Ninu ọrọ ileeṣẹ eto aabo Ghana, wọn ni awọn le fidi ẹ mulẹ, pe awon irinṣẹ to di awati naa jade lọna ti ko ba ofin mu ni.

"Ileeṣẹ ologun ilẹ Ghana ni ilana ti wọn maa n tọ lati taari nnkan elo si ajọ yoowu ti wọn ba fẹẹ fi ranṣẹ si. "

Igbakeji minisita to n ri si ọrọ aabo, Ernest Brogya Genfi, lo ṣalaye bẹẹ lori eto kan TV3, lalẹ ọjọ Aje.

O ṣalaye pe wọn ko ri ilana to tọ ti ẹgbẹlẹgbẹ nnkan ija fi di awati, bẹẹ ni ko si akọsilẹ kankan ti ijọba le fi mọ bi wọn ṣe poora ṣiwaju idibo to waye.

'Kò ṣòro láti mọ ibi tí àwọn nńkan ìjà náà wà'

Ninu ọrọ tirẹ, igbakeji minisita eto aabo lasiko ijọba Aarẹ ana, Nana Akufo-Addo, Kofi Amankwah-Manu, sọ pe ki i ṣe ohun to nira lati mọ ibi ti awọn irinṣẹ ogun naa wa.

O ni o ya oun lẹnu bi minisita eto aabo to wa nipo bayii ṣe gbe ọrọ naa de igboro aye.

" Ko ṣoro rara lati mọ ibi ti awọn irinṣẹ ogun naa wọlẹ si, ẹni to gbe wọn lọ ati ohun ti wọn n lo wọn fun."

Bẹẹ ni Kofi Amankwah-Manu.

Àlàyé àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nípa ààbò

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iwoye awọn eeyan to mọ nipa aabo lori iṣẹlẹ yii ni pe o ṣee ṣe ki awọn nnkan ija naa ti bọ sọwọ awọn eeyan ti ko yẹ ko bọ si rara.

Onimọ nipa aabo to ba BBC News Pidgin sọrọ, Richard Kumadoe, ṣalaye pe iṣẹlẹ naa ko ba laakaye mu fun orilẹẹde kan .

O ni iwadii to le gan-an gbọdọ waye lorii rẹ.

"Ajọ National investigation (BNI), lo yẹ ko dide si ọrọ yii, ki wọn si tanna iwadii sibi ti awọn nnkan ija ologun poora lọ."

O ṣalaye pe: "nibi ti wọn ba ti n lo iṣẹ ọpọlọ fun ọrọ aabo, o ni kinni kan ti wọn n pe ni pipa aṣẹ ati idari( command and control).

"Atọka ohunkohun ti wọn ba mu kuro nibi kan lasiko to ba n ṣẹlẹ leyi jẹ. O gbọdọ ni ẹni kan ti wọn maa gba mu lori rẹ."

"O le jẹ pe wọn ti ta awọn nnkan ija to poora yii fun awọn ti yoo fi okunkun boju ra a, wọn si le ti fun awọn awakusa lọna aitọ.

"Koda, wọn le fi fun awọn oloṣelu ati awọn fijilante. O ṣe pataki gan-an lati wa a."

Ọdun pipẹ ni orilẹede Ghana ti n koju awọn aigbọra ẹni ye kan lori ọrọ oye jijẹ.

Awọn onimọ lori aabo ṣalaye pe ipaniyan ti wọn ko ni mọ awọn to ṣe e, ki wọn maa yinbọn lasiko ija ati idigunjale ti n pọ si i.

Loṣu Kẹrin ọdun yii Christian Tetteh Yohuno, rọ awọn ọdọ to n ja fun Bawku lati ti ida wọn ba àkọ̀.

Bẹẹ ni awọn agbesunmọmi to n dunkooko lawọn ẹnu ibode Ghana wa nibẹ pẹlu.

Ohun to yẹ ni ki okun aabo le danin-danin lori ilẹ ati nibudo gbogbo lorilẹ ede naa, bi awọn eleto aabo ṣe sọ.