Ẹnìkan máa ń fún ni mílíọ̀nù kan náírà ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni mo ṣe fi iṣẹ́ tíátà sílẹ̀ fún ìgbà díẹ̀ - Nkechi Blessing

Nkechi Blessing Sunday

Oríṣun àwòrán, Nkechi Blessing Sunday/Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gbajúmọ̀ òṣèré tíátà, Nkechi Blessing Sunday ti ṣàlàyé ìdí tí kò fi kópa nínú eré sinimá fún ìgbà kan kó tó di pé ó padà báyìí.

Nkechi Blessing sọ pé òun fi iṣẹ́ tíátà sílẹ̀ fún ìgbà kan ná látàrí àti lè gbájúmọ́ àwọn òwò míì tí òun ń ṣe.

Ó ní lẹ́yìn náà ni àwọn ẹgbẹ́ Theatre Arts and Motion Pictures Practitioners Association of Nigeria (TAMPAN) fi òfin de òun láti máṣe kópa nínú eré mọ́.

Nígbà tó ń kópa níbi ètò 'Curiosity Made Me Ask' òṣèré náà ní ohun tó mú òun fi iṣẹ́ tíátà sílẹ̀ pátápátá lásìkò náà kò ṣẹ̀yìn bí èèyàn kan tí òun kò mọ̀ rí, ṣe ń fún òun ní mílíọ̀nù kan Naira ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀.

"Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń fojú kéré mi nídìí iṣẹ́ tíátà, ẹ̀yà ara mi ni wọ́n máa ń wò jùlọ dípò ìmọ̀ mi"

Nkechi Blessing ní tí òun bá ti sọ fún ẹni náà pé òun ń lọ sí oko eré, ni ẹni náà máa bèèrè iye tí wọ́n fẹ́ san fún òun.

O ni ẹni ọhun, ti ko darukọ rẹ, sì máa fún òun ní ìlọ́po owó náà to yẹ ki oun gba nibi ere sise, tó sì máa sọ fún òun pé kí òun jòkòó nílé.

Gbajumọ òṣèré tíátà náà sọ pé èyí kún ìdí tí òun kò ṣe fi bẹ́ẹ̀ kópa nínú sinimá lásìkò náà mọ́ àmọ́ tí òun ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣeré padà báyìí.

Nkechi Blessing tún wòye pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fojú kéré òun nídìí iṣẹ́ tíátà, tó sì jẹ́ pé ara òun ni wọ́n máa ń wò jùlọ dípò ìmọ̀ òun.

Ó wòye pé òṣèré tó dáńtọ́ ní òun àmọ́ àwọn èèyàn kìí rí òun bẹ́ẹ̀.

"Mo lérò pé èyí rí bẹ́ẹ̀ nítorí nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ eré tíátà, mo máa ń ṣe àfihàn àwọn ẹ̀yà ara tí ọlọ́run fún mi dáadáa.

"Nítorí náà, àwọn èèyàn kìí fi iyè sí bí mo ṣe máa ń ṣeré, ara mi ni àwọn èèyàn máa ń wò, mo sì ri pé ó dàbí pé èmi ni mo fà á, mò ń gbìyànjú láti mú àyípadà bá èyí."

Ta ni Nkechi Blessing?

Nkechi Blessing Sunday

Oríṣun àwòrán, Nkechi Blessing Sunday/Instagram

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kejì, ọdún 1989 ni wọ́n bí Nkechi Blessing Sunday.

Ọmọ ìpínlẹ̀ Abia ni Nkechi Blessing Sunday àmọ́ tó jẹ́ pé agbègbè Surulere ní ìpínlẹ̀ Eko ló gbé dàgbà

Ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Olu Abiodun Nursery and Primary school, kó tó tẹ̀síwájú lọ sí ilé ẹ̀kọ́ girama Barachel Model College.

Ní ọdún 2008 ló bẹ̀rẹ̀ eré tíátà lẹ́yìn tó parí ní ilé ẹ̀kọ́ fásitì Lagos State University nígbà tí ọ̀rẹ́ rẹ̀ Kemi Korede mú jẹ́ kó kópa nínú eré rẹ̀.

Ní ọdún 2012 ló di ìlúmọ̀ọ́ká pẹ̀lú ipa tó kó nínú sinimá Kafila Omo Ibadan.

Ọdún 2021 ló ní ìfaǹfà pẹ̀lú ẹgbẹ́ Theatre Arts and Motion Pictures Practitioners Association of Nigeria (TAMPAN) tí wọ́n sì fi òfin dè é láti yé kópa nínú eré mọ́.

Ìgbésẹ̀ náà ló wáyé nígbà tí òun àti akẹgbẹ́ rẹ̀ míì, Kehinde Adams tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Lege Miami ní ìfaǹfà lórí ayélujára lórí ọ̀rọ̀ Baba Ijesha.

Bí Nkechi Blessing ṣe bu ẹnu àtẹ́ lu TAMPAN nígbà náà ló jẹ́ kí wọ́n fi òfin dè é láti má kópa nínú eré mọ́.

Oṣù Kẹwàá ọdún 2024 ni wọ́n gbé ẹsẹ̀ kúrò lórí òfin tí wọ́n fi dè é lẹ́yìn tó tọrọ àforíjì lọ́wọ́ TAMPAN níbi ayẹyẹ kan tó wáyé ní orílẹ̀ èdè Canada.