Ohun tí a mọ̀ nípa àyẹ̀wò àwọn òṣìṣẹ́ 3,598 ní Nàìjíríà, lórí ẹ̀sùn fífowó ra iṣẹ́

Aworan Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Bola Ahmed Tinubu/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba apapọ ti paṣẹ pe ki oṣiṣẹ ijọba 3,598 ti wọn kuna lati ṣe ayẹwo iwe igbanisiṣẹ wọn atawọn iwe ẹri mii lọdun 2021 lati lọ fun ayẹwo ọtun bayii.

Igbesẹ yii waye latari oniruuru ẹsun pe ọpọ eeyan lo n sanwo lati gba iṣẹ ijọba apapọ tawọn mii si n fi iṣẹ ọba ṣe kata-kara.

Ọrọ yii wa ninu atẹjade kan ti akọwe agba ajọ FCSC to n ri si ọro awọn oṣiṣẹ ni Naijiria, Ndiomu Ebiogeh Philip, fi sita.

Ijọba kilọ pe ẹnikẹni to ba kọ lati ṣe bẹẹ yoo tumọ si iwe igbanisiṣẹ ayederu ni wọn n lo.

Ayẹwo yii ni ijọba kede wi pe yoo bẹrẹ lati ọjọ kejidinlogun oṣu Kẹjọ yii titi di ọjọ kejidinlọgbọn oṣu yii bakan naa.

Ninu atẹjade naa ni ijọba ti sọ fawọn oṣiṣẹ tọrọ kan lati lọ yẹ orukọ wọn wo lori itakun agbọrọkaye ajọ FCSC ati ti olori awọn oṣiṣẹ ni Naijiria.

Bakan naa ni ijọba tun sọ fawọn oṣiṣẹ naa lati lọ fun ayẹwo ọhun lawọn ileeṣẹ ijọba gbogbo.

Nnkan tawọn oṣiṣẹ tọrọ kan nilo fun ayẹwo

Lara awọn nnkan tawọn oṣiṣẹ tọrọ kan nilo fun ayẹwo ọhun ni iwe igbanisiṣẹ, iwe igbega lẹnu iṣẹ, iwe isọni di oṣiṣẹ ati ẹri owo oṣu Keje to kọja pẹlu ilana IPPIS.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn oṣiṣẹ ti ọrọ kan ni awọn to gba iṣẹ ijọba apapọ laarin ọdun 2013 si 2020 ti wọn kuna lati kopa ninu eto ayẹwo to waye lọdun 2021.

Ajọ FCSC sọ ninu atẹajde naa wi pe ''gbogbo oṣiṣẹ tọrọ kan gbọdọ tẹle ilana ayẹwo ọhun.

Awọn oṣiṣẹ yii gbọdọ lọ sibi ti wọn ti maa ṣe ayẹwo yii lọjọ ti wọn fun wọn.

Gbogbo awọn oṣiṣẹ yii ni lati wo orukọ wọn lori iwe orukọ ti ajọ FCSC fi ranṣẹ si gbogbo ẹka ileeṣẹ ijọba.''

Ajọ FCSC sọ pe oṣiṣẹ 592 ni ọrọ kan ni ẹka ileeṣẹ ijọba to n ri si eto iroyin, nigba ti oṣiṣẹ 506 ni lati ṣayẹwo naa nileeṣẹ ijọba to n ri si eto ẹkọ.

Ojile ni irinwo oṣiṣẹ ni yoo ṣe ayẹwo naa ni ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ awọn oṣiṣẹ.

Oṣiṣẹ 134 ni yoo ṣe ayẹwo naa ni ileeṣẹ ijọba to n ri si iṣẹ ode, 196 ni ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ileeṣẹ ati okowo ati196 nileeṣẹ eto ilera.

Ojilelugba din mẹta oṣiṣe lọrọ kan nileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ ayika, mẹrinlelogun nileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ abẹle, mejidinlọgbọn lẹka eto abo ati oṣiṣẹ mẹrindinlogoji lọọfiisi akọwe ijọba apapọ.