Wo bí ẹlẹ́wọ̀n 16 ṣe ṣá kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ní Nasarawa,

Aworan ọwọ ẹlẹwọn to fẹ sakuro

Oríṣun àwòrán, Joner IMAGES VIA Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ amojuto ọgba ẹwọn lorilẹede Naijiria ti fidi iroyin kan to n ja kaakiri mulẹ pe awọn ẹlẹwọn kan kọlu awọn ẹsọ alabo ni ọgba ẹwọn New Keffi, ni ipinlẹ Nasarawa lẹkun ariwa Naijiria ti wọn si fọ ọgba ẹwọn naa, salọ..

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ NCS, Umar Abubakar fi lede ni owurọ Ọjọ kejila oṣu kẹjọ ọdun 2025 lo ti fidi iroyin naa mulẹ.

O sọ ninu atẹjade pe awọn ẹlẹwọn yii kọlu ẹsọ alabo ọgba ẹwọn, to fi mọ awọn oṣiṣẹ ọgba ẹwọn lati sa kuro lọgba ẹwọn.

"Ẹlẹwọn mẹrindinlogun ṣaa kuro ni ahamọ. Bi awọn oṣiṣẹ ṣe n gbinyanju lati mojuto iṣẹlẹ, marun un ninu wọn farapa yanayana, ti meji ninu wọn si wa ni ile iwosan ijọba."

Abubakar ni awọn ti mu diẹ ninu awọn elẹwọn to saa kuro lọgba ẹwọn naa.

Ọga agba fun ajọ to n mojuto ọgba ẹlẹwọn, Sylvester Ndidi Nwakuche ṣabẹwo si ọgba ẹwọn naa, to si palaṣẹ pe ki iwadii bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.

Bakan naa lo gbe ikilọ kalẹ pe ti iwadii ba fihan pe oṣiṣẹ ọgba ẹwọn lọwọ ninu iṣẹlẹ naa, irufẹ eeyan yoo ri ijiya ofin.

Jija ọgba ẹwọn lorilẹede Naijiria

Ko din ni ẹgbẹrun marun un ẹlẹwọn to ti sa kuro ni awọn ọgba ẹwọn jakejado Naijiria lati ọdun 2020.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lara awọn iṣẹlẹ fifọ ọgba ẹwọn salọ to waye laipẹ julọ ni awọn Ẹlẹwọn mejila ti wọn ṣa kuro lọgba ẹwọn Kotonkarfe to wa nipinlẹ Kogi loṣu kẹta ọdun 2025.

Bi awọn ẹlẹwọn naa ṣe sa kuro lọgba ẹwọn ni a ko tii le fi idi rẹ mulẹ lasiko kiko iroyin yii jọ nitori aiti sọ ọrọ to kunna lori rẹ latọdọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọgba ẹwọn lorilẹede Naijiria.

Bakan naa ninu oṣu karun un, ko din ni ẹlẹwọn meje to ti sa kuro lọgba ẹwọn Ilesa, nipinlẹ Osun, latari ojo arọọda to rọ loru ọjọ Iṣẹgun, ogunjọ oṣu Karun-un ọdun 2025 yii.

Agbẹnusọ ọgba ẹwọn naa, Umar Abubakar, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ninu atẹjade to fi sita.

Abubakar ṣalaye pe awọn alaṣẹ ọgba ẹwọn naa ti bẹrẹ iṣẹ lorii bi wọn yoo ṣe ri awọn ẹlẹwọn yii mu pada sọgba ẹwọn.

Ẹwẹ ko din ni ọgọrun un ẹlẹwọn to raaye salọ kuro ni ọgba ẹwọn kan to wa ni ilu Suleja, nipinlẹ Niger lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024.

Ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹsan an, ọdun 2024,ni ileeṣẹ to n ri si ọgba ẹwọn ni Naijiria, NCS, kede pe ẹlẹwọn 281 lawọn ṣi n wa lẹyin ti wọn salọ kuro lọgba ẹwọn ilu Maiduguri, nipinlẹ Borno.