Kà nípa ọdún Ahérégbé tó jẹ́ ọjọ́ tí ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣí ṣọ́ọ̀bù tàbí tajà l'Akure

Aworan ọja ọba niluu Akure
Àkọlé àwòrán, Ko si ẹnikẹni to ṣi sọọbu lonii ọdun Aheregbe
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Wọn ti ṣe ọdun Aheregbe lonii niluu Akure, to wa nipinlẹ Ondo.

Iyalẹnu lo jẹ pe ilu Isinkan darapọ mọ ọdn Aheregbe tọdun yii.

Lasiko ọdun ọhun ni awọn agbagba ilu Akure maa n gbadura fun alaafia ilu naa, to fi mọ ilu Oba Ile, eyii ti ko fi bẹẹ jina si Akure.

Ko ni si kata-kara ninu awọn ilu memeji lasiko ti ọdun Aheregbe ati ọdun Amole yoo maa waye.

Ẹnikẹni to ba taja ni ayajọ ọdun naa le padanu ọja rẹ nitori awọn to n kaakiri ilu lati ri daju pe ọdun naa lọ bo ṣe yẹ ko lọ le ko ọja irufẹ ẹni bẹẹ.

To n tumọ si pe awọn to n kaakiri naa laṣẹ labẹ aṣa ilu Akure lati ko tabi gbẹsẹ le ọja irufẹ ọja tabi oniṣowo bẹẹ.

Bakan ni ilu yoo ko ọja awọn miran si aarin igboro pẹlu paṣan lọwọ ti wọn a si maa ko paṣan bo ẹnikẹni to ba tapa si ilana to rọ mọ ọdun ọhun, bii ṣiṣi ṣọọbu.

Kí ni ìdí tí Isinkan fi kópa nínú ọdún Aheregbe ọdún yìí?

Ọja isinkan, Akure

Ìyàlẹ́nu lo jẹ pe Isinkan darapọ̀ mọ̀ ọdún Aheregbe ọdún yí, kí ló jẹ́ kí wọn ti àwọn ilé ìtajá ni Isinkan

Iyalẹnu nla lo jẹ pe ọja ati gbogbo awọn ile itaja wa ni titi pa loni ni Isinkan.

Saaju ọdun yii ni wahala ati ija ti maa n waye laarin Isinkan ati Akure latari ọdun Aheregbe nitori ilu Isinkan ma n si gbogbo ọja wọn ati awọn ile itaja ni ayajọ oni.

Lasiko ti BBC kan si Aafin Iralepo Isinkan, ọkan lara awọn oloye Isinkan, ti ko fẹ ki orukọ rẹ di mimọ ṣalaye pe, ipade waye lọjọ Aje ọsẹ yii laarin awọn lọbalọba lagbegbe Akure.

O ṣalaye pe, wọn ni adehun pe wọn gbọdọ bọwọ fun ofin ati ilana ọdun Aheregbe tọdun yii ki alaafia le jọba.

O sọ fun BBC Yoruba pe wọn nilo lati gbe igbese yii latari oniruru awuyewuye to ti waye, ki alaafia le jọba.

O rọ gbogbo awọn olugbe Isinkan ati agbegbe rẹ lati bọwọ fun aṣa ati iṣe ọdun naa, fun alaafia ilu Akure lapapọ.

Kí ni pàtàkì ọdún Aheregbe?

Deji ilu Akure lo ma n kede ọdun naa, bo tilẹ jẹ pe ọpọlọpọ lo ri ọdun naa gẹgẹ bi ohun ti ko tọna, to si n di ọrọ aje awọn eniyan lọwọ.

Ṣugbọn awọn oniṣẹṣe ri ọdun ọhun gẹgẹ bii ohun to pọn dandan lati le jẹ ki alaafia jọba niluu Akure ati agbegbe rẹ.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, Oloye Sao ilu Akure, Olaniyi Ajongbolo ṣalaye pe, wọn ya ayajọ oni sọtọ fun akanṣe adura fun Akure ati agbegbe rẹ.

O ni wọn n ṣe ọdun naa ni ibamu pelu aṣa ati iṣe ilu Akure.

Oloye Sao sọ pe wọn ya ayajọ oni sọtọ lati gbadura fun Akure ki wahala tabi akọlu kankan ma ṣe sẹlẹ.

O rọ gbogbo olugbe Akure lati ṣe ọdun ọhun ni ibamu pẹlu gbogbo aṣa ati iṣe Akure ki alaafia le jọba.