Pásítọ̀ tó ń fi màrìwò ọ̀pẹ na ọmọdé fún 'ètò àdúrà' wọ gàù ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ pasitọ kan atawọn ọmọ ijọ rẹ ni ipinlẹ Rivers lori ẹsun hihu iwa aitọ si awọn ọmọde.
Bakan naa ni wọn tun doola ọmọde kan to ti wọn n na ni ina bara ni ile ijọsin kan ni agbegbe Eneka ni ipinlẹ naa.
Orukọ pasitọ ti wọn mu ni Ifediorah Joseph, ti ijọ Our Lord Victory Covenant Mission ni ilu Eneka ni ipinlẹ Rivers, lẹkun iwọ oorun Naijiria.
Awọn agbalagba mẹta miran naa wa ninu fọran naa. Bi wọn si ṣe n fi imọ ọpẹ na awọn ọmọde naa ni wọn n kọ orin tabi ọawọn ede kan bi pasitọ naa ṣe n yi wọn ka.
Fidio kan to gbode lori ayelujara lo ṣokun mimu Pasitọ naa
Ọlọpaa mu awọn eeyan naa lẹyin ti fidio kan lu ayelujara pa lọjọru ninu eyi ti pasitọ kan ti n fi imọ ọpẹ na awọn ọmọde kan ti wọn bọ si ihoho.
Ko daju asiko ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, bi o tilẹ jẹ wi pe awọn agbofinro sọ pe ọrọ ẹsin lọrọ naa fi ara jọ, ṣugbọn iwadii yoo waye lori rẹ.
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa gbe jade, wọn ni pasitọ naa to jẹ ẹni ọdun mọkanlelogoji gbe ipade ọlọjọ mẹta kan kalẹ fun awọn ọmọde ninu ijọ naa fun "iwẹnumọ ẹmi" eleyii to ni bi Ẹmi Mimọ ṣe dari oun ni.
"Ni kete ti iroyin yii tẹ wa leti, awọn ọlọpaa lati ẹkun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers fi panpẹ ofin mu pasitọ naa ati ọpọlọpọ awọn ọmọijọ rẹ.
Ori ikunlẹ lawọn ọmọ naa wa ti pasitọ ọhun si n fi imọ ọpẹ na wọn ni ihoho ọmọluabi. Koda bo ba ti na awọn miran tan ninu wọn ni yoo ju wọn si awọn kan lara awọn ọmọ ijọ naa fun 'iwẹmọ' ọhun.
Awọn aladugbo to wa ni ile kan nitosi ni wọn ya fidio iṣlẹ ọhun ti wọn si pariwo sita lori ohun to n ṣẹlẹ ni ile ijọsin naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Awọn obi n ṣe atilẹyin fun pasitọ
Iyalẹnu nla to wa nidi ọrọ naa ni peọpọlọpọ awọn obi awọn ọmọ ti rọ naa kan ni wọn ya bo agọ ọlọpaa to wa ni agbegbe Eneka, pẹlu orin ati ijo lati fi ṣegbe lẹyin pasitọ naa.
Wọn ṣalaye wi pe funra awọn lawọn fi ọwọ si eto iwẹnumọ naa ti wọn si n pariwo pe pasitọ naa ko fi ipa ṣe ohunkohun pẹlu awọn ọmde naa.
Ọkan lara awọn obi naa, Arabinrin Ngozi Uzoma ṣalaye fun awọn akọroyin pe eto adura ti wọn n ṣe fun awọn ọmọ naa ko la ewu kankan lọ rara.
Pasitọ ni ko si ijamba ninu ohun ti oun ṣe
Ninu ọrọ to ba awọn akọroyin sọ, Pasitọ Ifedorah ṣalaye pe pẹlu atilẹyin awọn obi awọn ọmọ naa loun fi ṣe ohun ti oun ṣe ati wi pe wọn ṣe eto adura ọhun lati wẹ awọn ọmọ naa kuro ninu ewu ni.
Ajọ NAPTIP fariga, wọn ni iwadii gbọdọ waye
Ajọ to n gbogun ti ilokulo ati hihu iwa kotọ si ọmọniyan lorilẹede Naijiria, NAPTIP pẹlu ni awọn ti darapọ mọ iwadii lori iṣẹlẹ naa.
Alamojuto iṣẹ iwadii ni ajọ NAPTIP, Komani Timipire ni, pe obi fi ọwọ si igbesẹ bẹẹ ko sọ pe o lẹtọ lati tẹ ẹtọ awọn ọmọde naa mọlẹ ati pe iwa hihu iwa kotọ si ẹtọ ọmọde ni wọn yoo ka iṣẹlẹ naa si















