Aisha Lawal: Odidi ọdún mẹ́ta ni mo fi ń yá owó jẹun nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ ìṣẹ́ tíátà

Aisha Lawal

Oríṣun àwòrán, @aishalawal1

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajumọ oṣere, Aisha Lawal ba BBC Yoruba lalejo, o ṣi dahun ọpọlọpọ ibeere nipa igbe aye rẹ gẹgẹ bi oṣere lati igba to ti bẹrẹ ati awọn nnkan mii.

Ninu ifọrọwero naa ti pupọ awọn ololufẹ rẹ ti darapọ mọ wa ni Aisha ti tu pẹrẹpẹrẹ ọrọ nipa awọn iriri rẹ, gẹgẹ bi oṣere, iyawo ile, ati bẹbẹ lọ.

Iṣẹ amofin ni Aisha kọ ni ibẹrẹ aye rẹ, ko to di pe ori gbe e lọ sidi iṣẹ ere tiata agbelewo.

Fidio ifọwanilnuwo pẹlu Aisha Lawal naa ree:

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post

O ni olukọ rẹ kan lo gba awọn nimọran gẹgẹ bi akẹkọ imọ ofin lati wa kun iṣẹ wọn nitori bi ọrọ aje orilẹede yii ṣe ri, ki o to di pe o ya sidi iṣẹ tiata.

Lara awọn ohun toju rẹ ri nigba to n kọṣẹ tiata ni bii kii ṣe ma n si owo lọwọ rẹ nigba naa lọhun.

O sọ fun BBC pe "Nigba yẹn, iṣẹ lari ṣugbọn ko sowo."

Aisha Lawal

Akoko naa le to bẹẹ to jẹ pe o ku diẹ ko fi iṣẹ tiata silẹ, ṣugbọn awọn agba sọ pe ibi ori dani si laagbe.

Ọmọ bibi ilu Ibadan naa ni, lara adojukọ igba naa ni pe iṣẹ naa ko jẹ ki oun tete ri ọkunrin dimu, nitori pe awon ọkunrin toun ma n pade ma n ro pe, oun ti laju ju nitori iṣe to yan laayo.

Lori ọrọ ibaradọgba laarin ọkunrin ati obinrin, Aisha gbabọ pe, obinrin ko lee parada di ọkunrin, ṣugbọn ohun to ṣe pataki ni ki ọkọ bọwọ fun aya rẹ.

Aisha ni ipa ti eeyan ba ko ninu ere ko tunmọ pe, ohun naa yoo ṣẹlẹ si iru ẹni bẹẹ loju aye.

Àkọlé fídíò, Human trafficking: Iṣẹ́ irun ṣíṣe ló di iṣẹ́ aṣẹ́wó

O ni "Ni igba miran a ma n sun sinu posi ninu ere, eyi ko tumọ si pe a maa ku, ṣebi igi ni wọn fi kan posi. Ọlọrun majẹ ki aye lọwọ sọrọ eeyan."

Ọmọ ọdun marundinlọgbọn naa ni oun ko nifẹ si ki eeyan maa gbe gbogbo igbe aye rẹ soju opo ikansiraẹni lori itakun agbaye.

O ṣalaye pe "Iṣẹ tiata gba ki eeyan maa gbe ara rẹ sori ayelujara, ki awọn ololufẹ rẹ lee mọ pe o ṣi wa nigboro, ṣugbọn ni ti awọn ohun miran ti ko ba iṣẹ lọ, ti iṣu ẹni ba ta, a ma n dọwọ boo jẹ ni.

Aisha pari ọrọ rẹ pe, ki awọn ọdọ fi ti Ọlọrun ṣaaju ninu aye wọn, ati pe ki wọn ni ifarada, nitori ko si igba to le, ti ko ni dẹ.