Naijiria ati Ilẹ Amerika buwọ́lu ìwé àdéhùn lórí owó ìlú tí Abacha lù ní póńpó

ABACHA

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán, Àwọn orílẹ̀èdè mẹ́tà ní wọ́n jọ fọwọ́sowọ́pọ̀ láti buwọ́lú iwé àdéhùn láti ri wí pé wọ́n dá owó náà pádà.

Orilẹede Jersey, ijọba Naijiria ati ijọba orilẹede Amẹrika ti buwọlu iwe adehun pe wọn yoo ṣe lati da owo Naijiria to le ni ọọdunrun miliọnu ilẹ okeere($308 million) pada.

Eyi ko ṣẹyin bi ilẹ Amẹrika ṣe fi si oju opo ikansiraẹni ile iṣẹ wọn to wa ni Naijiria.

Ọgọọrọ owo naa ni wọn lu ni jibiti nipasẹ ile owo ifowopamọsi to wa ni ilu Jersey, ni orukọ Doraville Properties Corporation, ti wọn fi orukọ ọmọ aarẹ Naijiria nigba kan ri , Ọgagun Sani Abacha gbe kalẹ.

Ni ọdun 2014, ile ẹjọ giga ni Washington DC, ni ilẹ Amẹrika gbe ẹsẹ le owo orilẹede Naijiria ti wọn lu ni ponpo lọdun 1993 si 1998, labẹ Ọgagun Sani Abacha.

Ọgagun Sani Abacha ati awọn ẹmẹwa rẹ ji owo iluto le ni ọgọrun un miliọnu dọla ti owo ilu lasiko ijọba rẹ, eleyii to ṣe akoba fun ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria.

Awọn ẹbi rẹ pẹlu ọmọ rẹ Ibrahim ati Mohammed Babangida lo parapọ lu owo ilu naa ni ponpo.

Lati ilẹ Amerika, Ilẹ Gẹẹsi, Faranse, Germany, Switzerland, Lichtenstein ati Luxembourg wa lara awọn orilẹede ti wọn fi owo ilu ti wọn lu ni ponpo si.

Igbesẹ ti awọn orilẹede mẹta gbe naa jẹ ọkan gboogi ti ibaṣepọ laarin Naijiria ati ilẹ okeere yori si,pẹlu bi wọn ṣe mura lati da owo ilu ti wọn lu ni ponpo pada.

Bakan naa ni ijọba Naijiria sọ wi pe awọn yoo gbe igbimọ dide lati ṣe ayẹwo awọn eto idagbasoke ilu ti wọn pinnu lati fi owo naa ṣe lẹyin ti wọn ba da a pada.

Awọn ile iṣẹ to n ri igbelarugẹ awujọ ko ni gbẹyin lati pese awọn ohun ti ijọba orilẹede Naijiria nilo lati mu ayipada ba awọn ẹka eto iṣẹ akanṣe, imọ ẹrọ, igbogun ti iwa jẹgudujẹra ati lilọ si oke okun ni ọna aitọ.