Kobe Bryant: Ọjọ́ pẹ́ tí ìjàmba ọkọ̀ òfurufu ti ń dá ẹ̀mí àwọn èèkàn àgbáyé légbodò

Awaiye iku o si, ọna ti onikaluku yoo gba lọ le yatọ ṣugbọn ohun to daju ni pe, gbogbo wa la maa ku.
Boya ẹyin naa ti ka iroyin to fọwọ kan eeyan lẹmi nipa iku ilumọọka elere bọọlu alapẹrẹ ọmọ ilẹ Amẹrika, Kobe Bryant, ti o waye ni ọjọ Aiku.
Bryant, ọmọ rẹ obinrin ati awọn meje miran lo ba iṣẹlẹ ijamba ọkọ ẹlikọpta to ja.
Igba akọkọ kọ niyi ti irufẹ ijamba ọkọ baalu ofurufu tabi ẹlikọpta yoo mẹmi awọn ilumọọka lọ.
Ẹ jẹ ki a ṣe ayẹwo awọ́n to ba iru iku bayi lọ:
Samora Machel
Aarẹ akọkọ ilẹ Mozambique ni Machel n ṣe.
Lọjọ kọkandinlogun oṣu Kẹwa ọdun 1986 lo si padanu ẹmi rẹ ninu ijamba ọkọ ofurufu to waye nigba ti baalu rẹ ja lẹba bode Mozambique pẹlu South Africa.

Oríṣun àwòrán, AFP
Ẹni ọdun mẹtalelaadọta nii ṣe nigba tọlọjọ de.
Oun ati eeyan mẹtalelọgbọn ni wọn ku ninu ijamba naa. Awọn mẹsan to joko sẹyin baalu naa moribọ ninu ijamba ọhun.
Aaliyah
Akọrin takasufe ọmọ ilẹ Amẹerika nii Aaliyah ti orukọ rẹ gangan n jẹ Aaliyah Dana Haughton, o si naa wa lara awọn to ba iṣẹlẹ ijamba ọkọ baalu lọ.
Lọjọ kẹẹdọgbọn oṣu Kẹjọ ọdun 2001 ni ọlọjọ mu oun ati awọn mẹjọ miran lọ nigba ti baalu wọn ja ni Bahamas.

Iwaadi fi han pe awakọ baalu naa, Luis Morales III ko ti gbawe aṣẹ lati le wa baalu, ti wọn si tun ri apẹrẹ ogun oloro cocaine ati ọti ninu ẹjẹ rẹ .
Kani pe Aliyah wa laye loni, ko ba pe ogoji ọdun.
Pius Adesanmi
Ni agbo awọn ọmọwe ni Naijiria, Pius Adesanmi ni ọpọ lero wi pe yoo jogun ọmọwe Wole Soyinka ṣugbọn iku ko jẹ.
Ni ọjọ kẹwa oṣu Kẹta ọdun 2019 ni ibanuje dori awọn ọmọ Naijiria kodo nigbati wọn gbọ ikede pe, ọkọ baalu Ethiopian Airline to gbera lati Ethiopia, ja lulẹ.
Ninu awọn eeyan mẹ́talelaadọrin to ku ninu ijamba yii ni ọmọwe Pius Adesanmi wa.

Oríṣun àwòrán, Adesanmi
Akọni onimọ litiresọ ede Gẹẹsi yi ko fi igba kan sinmi lati ma fi ọrọ rẹ pe akiyesi awọn alaṣẹ si kudiẹkudiẹ to n ba eto iṣelu.
Ọmọ bibi ilu Isanlu ni Pius Adesanmi jẹ ti o si fi iyawo,iya ati awọn ọmọ silẹ lọ.
Ẹni ọdun mẹtadinlaadọta ni lasiko ti o dagbere faye.
Vichai Srivaddhanaprabha:
Ẹgbẹ agbabọọlu Leicester City nilẹ Gẹẹsi wa lara awọn ẹgbẹ to pegede fi wọrọkọ jeka.
Aṣeyọri wọn ko si sẹyin bi baba olowo to ni ẹgbẹ naa ti ṣe gbaruku ti wọn.
O wa ṣeni laanu pe baba olowo ẹgbẹ agbabọọlu naa padanu ẹmi rẹ ninu ijamba ọkọ ofurufu ẹlikọpta, ni kete ti o gbera kuro ni papa iṣere Leicester City lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹwa 2018.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ni n ṣe ni ẹlikọpta naa n fi lakalaka, to si ja lulẹ, ti o si gbina.
Vichai ati awọn eeyan mẹta ti o wa ninu ọkọ naa pẹlu awakọ baalu ọhun ni wọn padanu ẹmi wọn.
Myles Munroe:
Ajihinrere Myles Munroe jẹ ilumọọka ti ọpọ eeyan si ma fi kan ba iwaasu rẹ bọ.
Ohun ni oludasilẹ ile ijọsin Bahamas Faith Ministries International (BFMI), tio si gba ọpọ ami ẹyẹ fun iṣẹ ajihinrere.

Oríṣun àwòrán, Google
Iku yọwọ rẹ lawo ninu ijamba ọkọ ofurufu kan to waye lọjọ kẹsan oṣu Kọkanla ọdun 2010.
Munroe, iyawo rẹ ati awọn eeyan mẹsan ni wọn ba iṣẹlẹ naa lọ.












