Ijọba ipinlẹ Ondo gbe agadagodo sẹnu ọna awọn ile ijọsin to tapa sofin konileogbele

Àkọlé fídíò, Ijọba ipinlẹ Ondo gbe agadagodo sẹnu ọna awọn ile ijọsin to tapa sofin konileogbele

Ijọba ipinlẹ Ondo gbe agadagodo sẹnu ọna awọn ile ijọsin to tapa sofin konileogbele lọjọ ọdun Ajinde.

Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ naa ti sọ pe oun wọgile ijọsin lọjọ ọdun naa, sibẹ awọn ijọ kan ṣe isin lọjọ ọdun ọhun.

Eyii lo mu ki awọn aṣọju ijọba lọ kaakiri ipinlẹ naa lati fi papmpẹ ofin mu gbogbo ile ijọsin to tapa sọfin ọhun.

Awọn ọnọ ijọ kan ni wọn ko gbọ pe ijọba ni ki wọn ma ṣe isin lọjọ naa, bẹ lawọn ijọ mii ti ilẹkun ile ijọsin wọn, ti wọn si ṣe sin ninu rẹ

Oluranlọwọ pataki funn ijọba ipinlẹ Ondo, Doyin Odebowale ṣeleri pe, gbogbo awọn pasitọ ti wọn gbamu ni yoo foju bale ẹjọ