Kaduna Forestry Students Kidnapping: Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sọ ìrírí wọn ní àhámọ́ ajínigbé fún ọjọ́ 56

Kaduna

Oríṣun àwòrán, Valentina Shekara

Idunnu subu lu ayọ fun awọn mọlẹbi ati ara awọn akẹkọọ mẹtadinlọgbọn lati ileewe Federal College of Forestry Mechanisation, Kaduna to jajabọ lọwọ awọn ajinigbe lẹyin ọjọ mẹrindinlọgọta ni ahamọ.

Amọ iriri wọn ni panpẹ ajinigbe buru jai, to jẹ wi pe niṣe ni wọn bu ṣẹkun lati sọ ohun ti oju wọn ri.

Nkan bi aago mẹta ọsan ni ariwọ sọ ni papa ibudokọ okọ ofurufu ni ilu Kaduba, ti awọn eniyan si fo fun ayọ lati ri awọn ọmọ wọn.

Ọkan lara awọn akẹkọọ naa to sọ iriri rẹ, Sarah Sunday ni awọn lọ si ọrun apaadi bọ ni pẹlu ohun to ṣẹlẹ si wọn.

''Wọn ko gba ki ẹnikẹni bu omi sara tabi lọ si baluwẹ ni ahamọ ọhun.''

Kaduna

Oríṣun àwòrán, Valentina Shekara

''Amọ wọn ko lu wa tabi pa ẹnikẹni ninu wa, ọ̀jọ kini ti a ti de bẹ ni wọn ti lu wa, ti wọn si ṣe fidio wa.''

''Bakan naa ni a o jẹun, ti a si rin rin rin ninu igbo aginju. Lẹyin ti awọn ọkunrin ba lọ pọn omi wa fun wa ni a o fi se ounjẹ Tuwo pẹlu Miyan kuka tabi Tuwo pẹlu Ila gbigbẹ''

''Igba kan pere la jẹ irẹsi ati spaghetti naa ni ahamọ awọn ajinigbe naa.''

Akẹkọbinrin miran to tun sọ iriri rẹ, Zakariya Mogaji ni awọn ohun to ṣẹlẹ si awọn gbẹnutan, ti wọn si fi iya jẹ awọn loriṣiriṣi.

Kaduna

Oríṣun àwòrán, Valentina Shekara

Arabinrin Magaji ni oun ko gbero iru nkan to ṣẹlẹ si oun fun ọta oun kankan nitori ko ṣee fi ẹnu sọ.

''Awọn ajinigbe yii nilo adura pe ki Ọlọrun fi ọwọ tọ wọn lọkan, amọ ni ti temi, mo ti dariji wọn.''

Kaduna

Oríṣun àwòrán, Valentina Shekara

Ninu ọrọ tirẹ, kọmisọnna ọlọpaa nipinlẹ Kaduna, Umar Muri ni awọn akẹkọọ to gba itusilẹ naa ti ṣe ayẹwo ara wọn finifini ni ileewosan, ti wọn si ni anfaani lati darapọ pẹlu awọn obi wọn.

Bakan naa ni o rọ wọn wi pe ki wọn ma jẹ ki iṣẹlẹ yii di wọn lọwọ ati pada si ileewe lati tẹpa mọ eto ẹkọ wọn.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Forestry college ti Kaduna Akẹ́kọ̀ọ́ 27 gba ìdáńdè lọ́wọ́ ajínigbé lẹ́yìn ọjọ 55

Olusegun Obasanjo ati Sheik Gumi

Awọn akẹkọọ mẹtadinlọgbọn to gba itusilẹ naa wa lara awọn mẹtadinlogoji ti wọn jigbe ni nkan bi oṣu meji sẹyin ni ileewe wọn.

Awọn akẹkọọ mẹtadinlọgbọn lati ileewe giga Federal College of Forestry ni Afaka, Kaduna ti gba itusilẹ lọwọ awọn ajinigbe.

Ileeṣẹ iroyin Daily Trust fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ nigba ti wọn ba ọkan lara awọn to ṣe oniduro awọn ti wọn tu silẹ naa sọrọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Iroyin naa ni gbajugbaja oniwaasu Islam, Sheikh Ahmed Gumi pẹlu iranwọ aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹ, Olusegun Obasanjo lo se eto bi awọn akẹkọọ naa ṣe gba itusilẹ.

Awọn akẹkọọ mẹtadinlọgbọn to gba itusilẹ naa wa lara awọn mẹtadinlogoji ti wọn jigbe ni nkan bi oṣu meji sẹyin ni ileewe wọn.

Àkọlé fídíò, India Corona scourge: Àlàyé rèé lórí ohun tó ń fa bí kòkòrò COVID-19 India ṣe búrẹ̀kẹ̀

Iroyin ni awọn mẹwaa ni awọn agbebọn naa kọkọ tu silẹ, lẹyin ti awọn obi ati alaṣẹ ileewe san owo ẹmi awọn ọmọ naa.

Awọn agbebọn naa kọkọ beere owo to to ẹẹdẹgbẹ miliọnu lọwọ ijọba ipinlẹ Kaduna, ki wọn to fi awọn ọmọ naa silẹ.

Amọ ijọba kọ lati duna dura pẹlu wọn, pẹlu ileri wi pe pipa lo tọ si wọn.

Amin iyasọtọ kan

Boko Haram ló jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásitì Greenfield gbé, kìí ṣe àwọn agbébọn ajínigbé lásán- Gumi

Sheikh Gumi

Gbajumọ olori ẹsin musulumi kan lorilẹede Naijiria, Ahmad Gumi ni awọn agbebọn Boko Haram lo ji awọn akẹkọọ fasiti Greenfield nilu Kaduna gbe.

O ṣalaye lori eto ileeṣẹ mohunmaworan AIT pe ọrọ ijinigbe awọn akẹkọọ naa ti n dojuru bi ẹsẹ telọ.

Ni ọjọ kejidinlogun oṣu kẹrin ọdun 2021 lawọn agbebọn ji ọpọlọpọ awọn akẹkọọ gbe nileewe fasiti Greenfield ni ilu Kaduna.

Abawọle fasiti Greenfield

Oríṣun àwòrán, other

Wọn ti pa lara awọn ọmọ naa ti wọn si tun n lerileka pe bi ijọba ko ba ko owo itusilẹ ọgọrun miliọnu naira wa pẹlu ọkada tuntun mẹwaa, pipa lawọn yoo pa awọn akẹkọọ to ku.

Alfaa Gumi ni awọn agbebọn Bokoharam naa ti n wọnu awọn agbebọn to n ji eeyan gbe kaakiri lorilẹede Naijiria bayii.

"Ọrọ naa ti n dojuru gidigidi bayii nitori awọn kan naa ti n lọwọ sii; Boko Haram ti n wọnu ọrọ yii bayii. Awọn gan ni wọn ji awọn akẹkọọ fasiti Greenfield gbe. Ọrọ orun ko si mọ bayii afi ka tete gbe igbesẹ lori rẹ ni kiakia."

O wa rọ banki apapọ orilẹede Naijiria lati san owo ti wọn beere fun naa.

O woye pe lootọ owo to gọbọi ni ọgọrun miliọnu naira ti wọn n beere fun ṣugbọn ko si owo to pọ ju lati san fun ẹmi awọn akẹkọọ naa