BBC Yollywood Roundup: Wo àkójọpọ̀ ìròyìn lágbo òṣèré tíátà Yorùbá lọ́sẹ̀ yii

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/SALAWA ABENI
Nnkan ayọ waye lọpọlọpọ lagbo oṣere tiata Yoruba lọsẹ yii.
Bi awọn kan se n se ọjọ ibi, bimọ tuntun, ni ẹlomiran ranti iku iya rẹ nigba ti awọn gbajumọ osere miran n gba ọrọ Baba ijesha mọ ara wọn lọwọ bi ẹni gba igba ọti.
BBC Yoruba ti wa se akojọpọ awọn isẹlẹ to waye lagbo awọn osere tiata lọsẹ yii, diẹ lara rẹ ree.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹbí Adeboye kéde bí ìlànà ikú Pásítọ Dare yoo ṣe lọ
- Ikú Dare Adeboye kò ní ǹkankan ṣe pẹ̀lú Covid-19, a bẹ̀bẹ̀ láti dá wà lákòókò yìí - Ẹbi Adeboye
- Àwọn ǹkan tí o kò gbọ́ rí nípa Dare Adeboye tó kú
- Mo dákú rangbọndan lẹ̀yìn tí amúgbálẹ́gbẹ gómìnà Akeredolu fún mi ní ìgbájú olóyì - Aláboyún
- Iléẹjọ́ pàṣẹ pé kí Makinde san N20m lórí bo ṣe dáwọn alága káńsù APC l'Oyo dúró lọ́nà àìtọ́
- Ọba Tejuosho tẹ ojú lọ́balọ́ba mọ́lẹ̀ fún ṣíṣe jìbìtì ìfẹ́ orí ayélujára - Ìgbìmọ̀ Afọbajẹ
- Ẹbí Fela Anikulapo yarí fún APC àti Tinubu torí èròjà ìpolongo ìbò
Bukunmi Oluwasina ṣe ọjọ ibi
Gbajumọ oṣere, Bukunmi Oluwaṣina le ọdun kan loke eepẹ ni ọjọ Keje oṣu Karun, ọpọlọpọ awọn oṣere ẹgbẹ rẹ lo si n kii ku oriire.
Bukunmi fi sita loju opo rẹ pe, nnkan ti oun beere lọwọ Ọlọrun lasiko ọjọ ibi oun lọdun 2020, lo ti ṣe fun oun.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 1
O ni oun ati ọkọ oun beere fun asọkalẹ anfani oyun ti oun ni nigba naay, ti Ọlọrun si ṣe e ni wẹrẹ.
Nibayii ọpọ awọn akẹẹgbẹ rẹ lagbo amuludun ni wọn ti n kii ku oriire naa.
Fẹmi adebayọ, Woli agba, Kunle Afod, Tawa Ajisefini, Wunmi Ajiboye, pẹlu Wumi Toriọla titi kan Mr Macaroni ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn ti kii ku oriire.

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Lizzy Anjọrin bimọ tuntun

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/LIZZYANJORIN
Ni ọjọ kini oṣu karun ọdun 2021 ni Lizzy Anjọrin ati ọkọ rẹ gbalejo ọmọ tuntun.
Lizzy fi fidio ti ounj ati ọkọ rẹ ti n dọwẹkẹ nigba to wa ninu oyun si oju opo Instagram rẹ.
''Oba aṣekan maku tun ti ṣe e, O maa n wo ọkan dajọ.
Ki i dajọ pẹlu ohun ti awọn eeyan ba n sọ nipa eeyan, oba pakanmire ti pa ẹgan mi rẹ patapata.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 2
Lizzy ni ''ẹ darapọ mọ wa lati ṣajọyọ oore ti Ọlọrun ṣe fun wa.
Ọlọrun tun ti bukun wa lẹẹkan sii, iyin ni gbogbo rẹ ja si, ALIHAMDULILLAH.
Ọjọ kinni oṣu karun un ọdun 2021 niluu Miami nipinlẹ Florida lorilẹede Amerika lo ti ṣẹlẹ.''
Lizzy ko sọ bo ya ọkunrin tabi obinrin ni ọmọ ti Eleduwa fi jinki oun ati ọkọ rẹ naa.
Bolanle Ninalowo naa ṣe ọjọ ibi ati ayajọ igbeyawo

Oríṣun àwòrán, Instagram/ninalowo
Ọjọ keje oṣu kẹfa naa ni ọjọ ibi gbajumọ oṣere tiata, Bọlanle Ninalowo, ti ọpọ eeyan tun maa n pe ni Makanaki.
Ninalowo kede ọjọ ibi rẹ pẹlu fidio kan ti oun ati iyawo rẹ ti n fẹnuko ara wọn lẹnu loju opo Instagram rẹ.
Awọn agba oṣere bii Allwell Adedamola, Ajibọla Alabi Pauma, Iteledicon, Bukunmi Oluwasina ati bẹẹbẹẹ lọ ni wọn ti kii ku oriire ọjọ ibi rẹ.

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Iranti iku oloogbe Funmi Martin

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Gbajumọ oṣere ni Funmi Martin ki o to jade laye.
Ọjọ kẹfa oṣu karun un ọdun 2002 ni Funmi Martin jade laye lasiko aisan ranpẹ.
Ni ọjọ kẹfa oṣu karun ọdun 2021 lo pe ọdun mọkandinlogun ti oloogbe naa ti re ibi agba a re.
Ọmọ rẹ Mide Martins, ti oun pẹlu jẹ gbajugbaja oṣere tiata naa fi iranti iya rẹ sita loju opo instagram rẹ:
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post, 3
"DIDUN DIDUN NI IRANTI OLODODO
Maa sun lookan aya ẹlẹda rẹ
Anikẹ Florence Funmi Martins Abiamọ tootọ
Aye yii fẹran rẹ ṣugbọn Ọlọrun fẹran rẹ ju wa lọ
Maa simi ANIKE IYA NI WURA MI"
Pasuma fi orin ki Salawa Abẹni lọjọ ibi rẹ.

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM/SALAWA ABENI
Ọkan lara awọn eekan manigbagbe olorin ni Waka Queen, Abẹni Salawa.
Ọjọ karun un oṣu karun un ọdun 2021 ni Salawa Abẹni pe ẹni ọgọta ọdun.
Lara awọn eekan to si kọrin ki, ti wọn si tun kii ni 'Ọganla Fuji' Wasiu Alabi Pasuma wa.
Ninu fidio kan ti Salawa Abẹni fi si oju opo Instagram rẹ, ni Pasuma ti ṣe afihan ara rẹ ni ile Salawa nibi to ti n kọrin kii ku ọdun ti Salawa naa si n jo.














