Idaho School Shooting; Ọmọ ọdún mọ́kànlá yìnbọn mọ́ èèyàn mẹ́ta níléèwé

Ileewe ti isẹlẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ọmọdebinrin kan tii se ọmọ ọdun mọkanla si mejila ni iroyin lo yinbọn lu awọn akẹgbẹ rẹ meji ni ileewe ati tisa ni ipinlẹ Idaho, lorilẹede Amẹrika.

Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ naa ni ọmọdebinrin ti wọn ko darukọ rẹ ọhun wa ni ipele kẹfa ni ileewe alakọbẹrẹ.

Ọmọdebinrin ọhun lo mu ibọn lọ si ileewe Idaho Middle School to si ṣina bolẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Eniyan mẹta to faragba ninu iṣẹlẹ naa ni awọn alaṣẹ sọ wi pe wọn ko ku, amọ wọn farapa.

Ọpẹlọpẹ olukọ obinrin miran lo jijakadi pẹlu ọmọdebinrin naa, to si gba ibọn lọwọ rẹ, ki awọn ọlọpaa to de lati fi panpẹ si lọwọ.

Aworan ilu ti ileewe naa wa ni Amẹrika

Ko tii han si ẹnikẹni idi ti ọmọ naa fi yinbọn lu akẹgbẹ ati olukọ rẹ.

Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni n ṣe ni ọmọdebinrin naa yọ ibọn kuro ninu baagi to gbe pọn, to si bẹrẹ si yin ibọn leralera ninu ileewe naa ati ita.

Bẹẹ si ni wọn bẹrẹ si ni gbọ ariwo kikan kikan lẹyin ti awọn to faragba ninu iṣẹlẹ naa ṣiṣe.

Adari ileewe naa, Chad Martin ni ibanujẹ ọkan ni iṣẹlẹ to waye ni ileewe wọn jẹ fun gbogbo awọn ti ọrọ naa kan, amọ wọn dupẹ pe ko mu ẹmi ẹnikẹni lọ.

Àkọlé fídíò, 'Ẹ kálọ sí ìlú mi'... Ètò ńlá tó bẹ̀ sílẹ̀ kìjà lórí BBC Yorùbá

Bakan naa ni wọn ti paṣẹ lati ti ileewe naa pa ni Ọjọ Ẹti, amọ awọn olubadamọran yoo wa ni ikalẹ lati ba awọn akẹkọọ sọrọ.

Ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ lorilẹede Amerika, FBI ati ọlọpaa abẹlẹ ni iwadii ti bẹrẹ ni pẹrẹwu lori iṣẹlẹ naa.