World AIDS Day: Ẹ̀jẹ̀ àti àtọ̀ mi dàbí májèlé lẹ́yìnn ti mó kó àrùn kògbóògùn - Christopher

Oríṣun àwòrán, Christopher Klettermayer
Emi gẹgẹ bí ẹnìkan, ọmọ ilẹ Yuroopu, mi o lero rara pe mo le ni arun HIV/AIDS.
Ọgbẹni Christopher Klettermayer, ọmọ orilẹede Austria to jẹ ọmọ ọdun mejidinlogoji lo sọrọ yii fún BBC.
Ọdun 2014 ni ayẹwo fihan pe Christopher ti ko arun HIV/AIDS.
Ọjọ náà sì tun dabi ana loju Christopher.
- Buhari, wá wí tẹnu rẹ lórí ohun tí ò ń ṣe nípa ètò àbò Naijiria - Ilé ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣòfin
- 'Àwọn agbébọn tó pá Olufon ti Ifon ti ṣe ohun èèwọ̀ ní ilẹ̀ Yoruba'
- Àwọn onímọ̀ ṣàlàyé àǹfàní tó wà nínú gbígba ajaguntà láti kojú Boko Haram
- Awakọ̀ agbókùú, ọlọ́pàá, ológun, oníròyìn ló máa ń kọ́kọ́ dìbò ní Ghana, bó ṣe ń lọ rèé
Orileede India lo wa nigba naa nibi to ti n ṣiṣẹ gẹgẹ bí ayaworan-akọroyin.
O ti gbero lati lọ si agọ awọn ẹlẹsin Hindu, ọkan lara awọn àmúyẹ lati lanfaani de ibẹ ni ayẹwo HIV/AIDS.
"Nitori n kìí ṣe awọn ọkunrin to máa n ni ibalopọ pẹlu ọkunrin ẹgbẹ wọn, mo ti ro pe n ko le larun AIDS laelae," Christopher lo sọ bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eeyan 690,000 ni arun HIV AIDS ṣekupa lọdun 2019, ajọ eleto ilera agbaye, WHO tiẹ sọ pe, ajakalẹ arun covid-19 tun ti ṣakoba fún gbigbogun ti arun HIV AIDS.
Nigba ti o n sọ nipa ipenija to n doju kọ gẹgẹ bi alarun HIV, Christopher ni pe ọpọ ọrẹbinrin oun lo maa n beere bo ya awọn le ko arun naa lati ibi fifi ẹnu ko ẹnu.
Amọ, Christopher ni obinrin kan ya oun lẹnu lẹyin toun sọ fun un pe oun larun HIV, o ni niṣe lo sọ foun pe ko si wahala.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Arun HIV AIDS ko le ran eeyan nipa ifẹnukonu tabi itọ, tabi ninu ikọ, ninu ẹjẹ lo ti maa n ran.
Christopher ni oun l'ayọ bayii ju igba ti oun ko ti larun AIDS lọ.
O wa rọ àwọn to ba larun naa lati maa banujẹ, ki wọn ṣe ohun gbogbo ni pẹlẹpẹlẹ.
HIV AIDS ko ni ki eeyan ma gbe igbe aye to ni ìtumọ.
- Abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 tí Pfizer kéde ló fa ọ̀wọ́ngógó epo ní Naijiria - Ìjọba àpapọ̀
- Wo dókítà ọmọ Nàìjíríà tí àgbáyé ń wárí fún nítorí abẹ́rẹ́ àjẹsára COVID-19
- Ṣe lóòtọ́ ní ọmọ Nàíjíríà mílíọ́nù 25 yóò má ló ìná Solar látí Dec 1, 2020?
- Bí mo bá leè rí ọmọ alágbe t'áyé fẹnu sí pé mo fi ẹlẹ́rìndòdò lá lójú, máa kúnlẹ bẹ ẹ - Motara












