Ukraine war: 'Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Africa tí ebi n pa ló n jíyà ogun'

Oríṣun àwòrán, AFP
Olori ajọ awọn orilẹ-ede ilẹ Africa, to tun jẹ aarẹ Senegal , Macky Sall, sọ pe awọn orilẹede naa lo n jiya aimọdi, ninu ogun to n waye laarin Russia ati Ukraine.
Sall sọ ọrọ naa fun Aarẹ Vladimir Putin ti Russia, lasiko abẹwo to ṣe si nilu Sochi.
Lẹyin ijirioro naa, Macky Sall sọ pe olori orilẹ-ede russia ti ṣeleri lati jẹ ki wọn o ma a ko ounjẹ onkoro ati ajilẹ ranṣẹ silẹ okeere.
Amọ Putin sọ pe orilẹ-ede oun ko di Ukraine lọwọ lati ma ko ounjẹ onikoro lọ silẹ okeere.
O le ni ida ogoji ‘wheat’ ti ilẹ Africa n jẹ, to n wa lati Russia ati Ukraine.
ṣugbọn, lati igba ti ogun naa ti bẹrẹ ni wọn ti ti ibudokọ oju omi Black Sea, ti ko si si ẹrù kankan to n jade.
Ukraine fi ẹsun kan pe Russia lo ti ibudokọ omi naa.
Bakan naa ni oludari eto amojuto rogbodiyan ninu ajọ agbaye, Amin Awad, sọ nilu Geneva pe ìyàn yoo gbode, ti wọn ko ba fi ṣi awọn ibudokọ oju omi naa.
O ni ọwọn gogo ounjẹ onihoro le fi 1.4 biliọnu eeyan sinu ebi.
Nilẹ Africa, ogun naa ti da kun ọwọn gogo ounjẹ ti aisi eto aabo ati aisi ikore gidi.
Laipẹ yii ni orilẹ-ede Chad, kede nkan ofararọ lẹka ounjẹ, nitori pe ida mẹta awọn to wa lorilẹ-ede naa lo nilo iranlọwọ ounjẹ.
Aarẹ Sall sọ fun Putin pe lootọ ni awọn orilẹ-ede Africa jina sibi ti ogun ti n waye, amọ awọn ni iya rẹ n jẹ ju nipa ọrọ aje.
O ni oun tun bẹbẹ lorukọ awọn orilẹ-ede yooku to wa ni Asia, Middle East ati Latin America.
Putin sọ pe Russian ti ṣetan lati gba Ukraine laaye ko ko ounjẹ onikoro gba ibudokọ omi Azov ati Black sea. O ni ọna abayọ nla si eyi ni pe ki wọn o gbẹsẹ kuro lori ofin to de Belarus, alatilẹyin Russia, ki awọn ounjẹ naa le gba ibẹ kọja.
Awọn onwoye kan nipa ogun to n waye ọhun sọ pe Russia nireti pe ọwọn gogo ounjẹ, yoo di adanwo si awọn orilẹ-ede alawọ funfun lọrun, nigba ti awọn atipo lati Afirca ati Middle East ba yabo wọn nitori airi ounjẹ jẹ.














