Fashola: Omi ń bẹ lámù nídìí ìpèsè ina ọba

Babatunde Fasola ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Inà mọ̀nàmọ̀nà ti wà déédé láti ǹkan bíi osù méjì sẹ́yìn

Ibùdọ Amúnáwá ní Nàìjíríà tún ti kọsẹ́ lẹ́ẹ̀mejì láàrín ọjọ́ márùn ùn, bẹ́ẹ̀ iná ọ́ba ti ń se déédéé láti bíi osù méjì sẹ́yìn ní orílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Ìròyìn fihàn pé ó ti sẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀mẹfà níbẹ̀rẹ̀ ọdún 2018.

Báwo ló se sẹlẹ̀

Àkọsílẹ̀ láti ilé isẹ́ ìjọba àpapọ̀ tó ń rísí ọ̀rọ̀ isẹ́ òde, iná mọ̀nàmọ̀nà àti ilégbèé nílu Àbújà fihàn pé, Ibùdọ Amúnáwá da isẹ́ sílẹ̀ láàrín ọjọ́ kejìlá sí ọjọ́ kẹrìnlá, osù kẹrin ọdún yìí, èyí tó sì ń dààmú ìpèsè iná títí di ìsinyìí.

Ọjọ́ kínní osù kejì ló kọ́kọ́ sẹlẹ̀ lọ́dún yìí kó tó tún dákú padà báyìí.

Amin iyasọtọ kan

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí

Àkọlé fídíò, Ilẹ̀ gbígbẹ́ ní Bọ́ùn: Ìpìnlẹ̀ mẹ́fà leè má nìí iná ọba
Amin iyasọtọ kan

Ogbẹ́ni Usman Mohammed to je olùdarí ẹ̀ka tó ń pín iná mọ̀nàmọ̀nà ní Nàìjíríà wá pè fún àtúnse sí àwọn ohun eèlò tí wọn ń lò fi n mú iná wá pẹ̀lú àjọsepọ̀ àwọn olókoòwò ńlánlá láti ilẹ̀ òkèèrè.

Fasola gbà pé ìdàgbàsókè iná mọ̀nàmọ̀nà jẹ ìjọba lógún fún ilọsíwájú ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà pàápàá lásìkò yìí.