Coronavirus in Nigeria: Wòlíì 'Sọtítóbirẹ̀' fójú ba ilé ẹjọ́, fídíò ohun tójú rẹ̀ rí nílé ẹjọ́ nìyí
Awọn agba bọ wọn ni, ohun to n ṣe ilemboye kọ lo n ṣe ọmọ rẹ. Ilemboye n wa owo, ọmọ rẹ n wa ọkọ.
Iṣoro ṣe ọtọọtọ bayii fun gbajugbaja ojiṣẹ Ọlọrun ijọ Sọtitobirẹ ni ilu Akurẹ, Wolii Alfa babatunde bayii nitori bi gbogbo aye ṣe n du ori wọn ki wọn maa ko arun coronavirus ni Wolii Sotitobirẹ n du ori rẹ niwaju adajọ ile ẹjọ giga nilu Akurẹ.
- Èèyàn mẹ́jọ míràn tún ti ní àrùn Coronavirus ní Naijiria
- Èèyàn mẹ́jọ míràn tún ti ní àrùn Coronavirus ní Naijiria
- Kí ló pa bàbá Adeboye, bàbá Davido àti Ọ̀ọ̀ni Ifẹ̀ pọ̀ lásìkò ìgbélé l'Ọ́ṣun?
- Máfọ́ya, mo wà pẹ̀lú ẹ, Ajimọbi kàn sí Makinde lóri Coronavirus to ni
- Àwòrán ìhòhò: Salawa Abeni ti sọ̀rọ̀, ẹgbọ́ ohun tó wí
Woli Babatunde n jẹjọ ijinigbe ti wọọn fi kan oun atawọn ọmọ ijọ rẹ mẹfa lori ọmọde jojolo kan to poora ni ile ijọsin rẹ ni oṣu kọkanla ọdun 2019.
Wolii Sọtitobirẹ n pada si ile ẹjọ lẹyin ti igbẹjọ ti bẹrẹ ti awọn ẹlẹri gbogbo si ti n wi tẹnu wọn niwaju ile ẹjọ lati mọ boya ọwọ iranṣẹ Ọlọrun naa mọ tabi ko mọ lori ọrọ naa.

Akọroyin ileeṣẹ BBC News Yoruba to wa nibi igbẹjọ naa ṣalaye pe ki awọn afunrasi naa to wọ ile ẹjọ ni wọn ti kọkọ ni ki wọn fọ ọwọ wọn gẹgẹ bi ohun ti o n lọ lode bayii pẹlu ajakalẹ arun Coronavirus.
Bakan naa ni wọn ko jẹ ki akọroyin kankan wọle si yara igbẹjọ naa.









