Ọwọ ijọba ipinlẹ Ọyọ tẹ awọn eeyan mẹjọ kan to sọ ile ẹkọ ijọba di ileeṣẹ bulọku ati ile igbe

Awọn eeyan mẹjọ ọtọọtọ ti bẹrẹ sini fi oju wina ofin ijọba ipinlẹ Ọyọ nipasẹ lilo ayika awọn ile ẹkọ to jẹ ti ijọba lọna aitọ.
L'Ọjọ iṣẹgun kẹlẹ ijọba gbe awọn eeyan mẹjọ naa ni agbegbe Ologunẹru niluu Ibadan nibi ti wọn ri ẹrọ nla to n mọ bulọku si ni ayika ile ẹkọ kan to jẹ ti ijọba ipinlẹ Ọyọ.
Ile ẹkọ igbalode naa ti o di kikọ nipasẹ ajọṣepọ laarin ijọba apapọ ati ẹka eto ẹkọ nipinlẹ Ọyọ lo n bẹ ni ibudo idako Agbopa-Akufo ni ijọba ibilẹ Ido.
Ninu ọrọ rẹ lasiko irinkerindo lati ṣe amojuto awọn dukiya ijọba lasiko ti aarun Corona n ba gbogbo aye finra, alaga ẹka eto ẹkọ kalekako nipinlẹ Ọyọ, SUBEB, Ọmọwe Nureni Adeniran fi aidun inu rẹ han lorii
iwa kotọọ to n waye ni ninu ọgba ile ẹkọ naa gẹgẹ bi o ṣe n bura wi pe awọn to huwa ibajẹ naa ko ni lọ lai fi imu k'ata ofin.
Adeniran ṣe alaye wi pe awọn basejẹ naa ti ṣi ilekun ewu to pọ silẹ fun ile ẹkọ naa pẹlu afikun wi pe awọn yara ikẹkọọ, ile igbọnsẹ ati kọnga igbalode ti wọn kọ si ile ẹkọ naa ni awọn onile iṣẹ bulọku naa ti
bajẹ.
O ni, "Kodaa wọn ti sọ awọn yara ikẹkọọ di ibi ti wọn n sun si gẹgẹ bi wọn ṣe fọn gbogbo ohun ini wọn si ayika ile ẹkọ naa".

Adeniran tẹsiwaju wi pe, " ni awọn ikorita kan, awọn basejẹ yii ti sọ awọn dukiya ijọba ti ara wọn pẹluu bi o ṣe jẹ wi pe gbogbo awọn ile ẹkọ yii ni ijọba mọ odi yika.Niṣe ni wọn n fi ipa ṣe akoba fun awọn dukiya ijọba jakejado ipinlẹ Ọyọ".
Gẹgẹ bi Adeniran ṣe sọ, awọn eeyan mẹjọ to n ta ọjọ lọna aitọ ninu ọgba ile ẹkọ ijọba ni yoo fi oju ba ile ẹjọ ti wọn yoo si jẹjọ nilana ofin.
O ni eleyii yoo mu ki awọn basejẹ ti o ku so ewe agbejẹ mọwọ.
Iṣẹ iwadi fi han wi pe lati igba ti awọn ile ẹkọ ti di titi nitori aarun Corona ni awọn eeyan naa ti sọ ọgba ile ẹkọ ijọba di ile itaja.
Coronavirus in Nigeria: Makinde kò yan Buhari ní pọ̀ṣìn, síbẹ̀ kò léè máa kọ lẹ́tà ìfẹ́ síi nítorí ṣekárími-PDP

Oríṣun àwòrán, Seyi makinde
Ko si ija laarin gomina Seyi Makinde ati aarẹ Buhari.
Ẹgbẹ oṣelu PDP ti ke gbajare sita pe awọn ohun to n waye paapaajulọ lasiko ajakalẹ arun coronavirus to n waye lọwọ ko ni ohunkohun n ṣe eyi to lee tọka si pe gomina Makinde tabi ijọba ipinlẹ Ọyọ n wọ iya ija pẹlu ijọba apapọ atawọn ileeṣẹ rẹ gbogbo.
Atẹjade kan ti alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Ọyọ, Akeem Ọlatunji fi sita ṣalaye pe irọ ni gbogbo awọn to ba n sọ pe gomina Makinde n fi oju tẹmbẹlu ipo aarẹ n pa.
Ẹgbẹ oṣelu PDP fi kun un pe gbogbo awọn to n sọ ọ kaakiri pe gomina Makinde kii pe aarẹ tabi baa sọrọ ko sọ otitọ nitori ko si ofin to sọ pe ajọṣepọ tabi ajọsọ ọrọ to ba waye laarin Gomina Makinde ati aarẹ gbọdọ di eyi ti a n polongo fun aye ri.
O fi kun un pe ọfiisi kii ṣe eyi ti gbogbo awọn gomina ni lati maa fojojumọ kọ lẹta ifẹ ranṣẹ si.
Ẹgbẹ oṣelu APC lo ti kọkọ fi atẹjade sita ninu eyi to ti fẹsun kan gomina Makinde pe o n fi oju tẹmbẹlu ọfiisi aarẹ debi pe kii ni ibanisọrọ kankan pẹlu aarẹ.
Coronavirus in Nigeria: Gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, Abiọla Ajimọbi ránṣẹ́ ìkíni sí Seyi Makinde lórí àrùn COVID-19

Oríṣun àwòrán, Seyi makinde
Ni ọjọ Aje ni gomina ipinlẹ Ọyọ, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde kede pe oun pẹlu ti fara kaasa arun Coronavirus ati pe oun ti fi ara oun si igbele.
Ọkan-o-jọkan awọn ọmọ orilẹede Naijiria, paapaajulọ awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ ni wọn si ti n kii.
Pataki lara awọn to ti ki gomina naa ni Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi to fi ipo naa silẹ lọdun 2019.
Sẹnetọ Ajimọbi ni inu oun bajẹ gidigidi nigba ti oun gbọ iroyin pe Gomina Seyi Makinde ti ko arun ọhun.
Ninu atẹjade kan eyi to fi sita, Sẹnetọ Ajimọbi ni kete ti oun gbọ iroyin ni oun ti fi iṣẹ ma foya abo Ọlọrun wa pẹlu rẹ ranṣẹ si Gomina Makinde ni kete lẹyin to kede rẹ.
Sẹnetọ Ajimọbi kan sara si gomina ipinlẹ Ọyọ fun ọkan akin to ṣe lati kede fun araye pe oun naa ti ko arun ọhun.
Gomina ana nipinlẹ Ọyọ naa wa jẹ ko di mimọ faraalu pe, arun Coronavirus kii ṣe idajọ iku o, bo pẹ, bo ya ilẹ agbaye yoo bori rẹ.

Oríṣun àwòrán, Seyi makinde
Coronavirus in Nigeria: Seyi Makinde, gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ní ìpàdé ètò ọrọ̀ aje Nàìjíríà lòun ti kó àrùn COVID-19
Ni ọjọ aje ni gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde kede rẹ faye gbọ pe oun naa ti dara pọ mọ iye awọn to ti ko arun Coronavirus lorilẹede Naijiria.
Nnkan bii agogo marun abọ irọlẹ ọjọ Aje ni gomina Makinde tẹwọ gba esi ayẹwo rẹ ninu eyi to ti mọ pe oun ti ko arun naa.
Amọṣa nibo ni Makinde ti ko arun yii naa?

Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun gomina Makinde, Taiwo Adisa fi sita ṣalaye pe nibi ipade igbimọ ọrs aje lorilẹede Naijiria, NEC ni Makinde ti fẹrẹ ko arun ọhun.
Gomina Makinde wa lara awọn gomina to farahan nibi ipade igbimọ naa, gẹgẹ bi atẹjade ọhun ṣe sọ.
Ọjọ diẹ lẹyin ipade ọhun ni igbimọ awọn gomina lorilẹede Naijiria ba gba gbogbo awọn gomina to wa nibi ipade naa nimọran pe ki wọn lọ ṣe ayẹwo ara wọn nitori iroyin to n jade pe lara awọn to wa nibi ipade naa ti ko arun ọhun.
Iroyin ayẹwo Gomina Makinde yii n waye lẹyin ti wọn da ẹni akọkọ ti wọn kede pe o larun naa ni ipinlẹ Ọyọ silẹ.
Alabọde Amẹrika kan ni ẹni akọkọ ti wọn kede poe o ni arun naa nipinlẹ Ọyọ, wọn si ti daa silẹ pe ki o maa lọ sile bayii lẹyin itọju to peye ni ileewosan ti ayẹwo miran si ti fihan pe arun naa ti kuro ni agọ ara rẹ.















