Nigeria lockdown: Kí ni àwọn kókó tí Ààrẹ Buhari tẹnumọ́ nínú ọ̀rọ̀ tó bá àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ lọ́jọ́ Àìkú?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lootọ ni Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari ti kede pe ko ni si lilọ bibọ ọkọ ati eniyan nipinlẹ Eko, Ogun ati ilu Abuja, ṣugbọn ofin yii ko de awọn kan.
Eyi ko ṣẹyin bi iṣẹ wọn ṣe ṣe pataki si igbaye-gbadun awọn araalu.
Lara awọn eniyan naa lati ri awọn to n ṣiṣẹ ni awọn ileeṣẹ ẹrọ ibaraẹnisọrọ, awọn ileeṣẹ iroyin radio ati amohunmaworan, awọn oniweeroyin, to si le fi ẹri han pe awọn ko le ṣiṣẹ lati ile wọn.
Bakan naa ni ko yọ awọn ileeṣẹ to n ṣe nkan ti ẹnu njẹ, awọn ileepo bẹtiro, awọn ileeṣẹ eleto aabo ti ijọba ati aladani to fi mọ ileeṣẹ amunawa.
Eyi ko yọ awọn oṣiṣẹ ileewosan, awọn ile itaja ogun silẹ.
Ẹwẹ, iaarẹ sọ pe awọn ọkọ ti yoo lanfaani lati rin loju popo ni awọn ọkọ to ba ko ounjẹ ati ohun eelo itọju alaisan.

Wo ìdí tí Buhari ṣe gbẹ́sẹ̀ lé lílọ bíbọ̀ ní Eko, Ogun àti Abuja

Oríṣun àwòrán, The Guardian
Aarẹ Muhammadu Buhari ti kede awọn igbesẹ tuntun lori ọna ati wawọ ajakalẹ arun Coronavirus lorilẹede Naijiria.
Aarẹ Buhari ni awọn igbesẹ naa da lori amọran ileeṣẹ eto ilera nijọba apapọ ati ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun lorilẹede Naijiria
- Ààrẹ Buhari: Kò ní sí lilọ bibọ ni Eko,Ogun ati Abuja fọjọ́ mẹ́rìnlá gbako
- Èèyàn mẹ́rìnlà míràn tún ti ní àrùn Coronavirus ní Naijiria
- Èèyàn mẹ́rin míì tún ni Coronavirus nípìnlẹ́ Oyo, ó di èèyàn 97 tó níi ní Nàìjíríà
- Irọ́ ní, kìí ṣe àdó olóró ló bú gbàmù ní Akure - Ọ̀gá Ọ̀lọ́pàá Ondo!
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko bẹ̀rẹ̀ oúnjẹ pínpín fún àwọn èèyàn lásìkò ìgbélé Coronavirus
Aarẹ ni lootọ inira pupọ ni igbesẹ yii yoo mu ba awọn ọmọ orilẹede Naijiria ṣugbọn ọrọ arun coronavirus lorilẹede Naijiria bayii ti di tiku-tiye; o ti di ọrọ sunnukun to nilo amojuto pẹlu oju sunnukun.
Aarẹ ni pẹlu bi nnkan ṣe yọri si fun awọn eeyan orilẹede bii Italy ati Faranse, ko si ifarada to pọju fun ati koju aru naa ko to gba aorilẹede Naijiria kan.
Awọn igbesẹ ti aarẹ kede niwọnyii.

Oríṣun àwòrán, Bashir Ahmad
- Konile o gbele ni Ipinlẹ Eko, Ogun ati olu ilu Naijiria, Abuja
- Ko ni si irinna yoowu bi o ti wulẹ o mọ ni ipinlẹ Eko, Ogun ati olu ilu ilẹẹwa, Abuja fun ọjọ mẹrinla.
- Aarẹ Buhari ni aṣẹ konilegbele yii yoo bẹrẹ si nii fidi mulẹ, bẹrẹ lati agogo mọkanla alẹ ọjọ Aje, Ọgbọn ọjọ oṣu kẹta, ọdun 2020.
- Lasiko yii, ko gbọdọ si lilọ bibọ ọkọ tabi eeyan. Olukukluku ni ko gbe ile rẹ.
- Ko ni si irinna ọkọ lati ipinlẹ si ipinlẹ tabi ilu si ilu lawọn ipinlẹ ti aṣẹ igbele naa ba wi.
- Gbogbo ileeṣẹ ati ibudokoowo gbogbo ni yoo wa ni titi pa lawọn ipinlẹ ti aṣẹ naa kan.
- Gbogbo lilọ bibọ ọkọ ofurufu akero ati aladani gbọdọ dopin bayii ati pe aṣẹ irinna yoo wa fawọn to ba ṣe pataki fun.
Awọn wo ni aṣẹ yii yọ silẹ?

Oríṣun àwòrán, Bashir Ahmad
- Aṣẹ tuntun ti aarẹ ṣẹṣẹ pa yii yoo yọ awọn ileewosan ati gbogbo awọn ileeṣẹ to nii ṣe pẹlu eto iwosan ati iṣegun silẹ.
- Bakan naa ni aṣẹlẹ isede naa ko tun ni kan awọn ileeṣẹ itaounjẹ
- Ileeṣẹ to n ta epo bẹntiro
- Ileeṣẹ ina mọnamọna
- Bakan naa ni aarẹ Buhari tun ṣalaye pe awọn ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ, igbohunsafẹfẹ, iwe iroyin to ba lee fi idi rẹ mulẹ pe awsn ko lee ṣe iṣẹ awọn lati ile pẹlu ko ni si labẹ aṣẹ konilegbele yii.
Ki ni awọn igbesẹ tii yoo waye lasiko igbele yii?

Oríṣun àwòrán, lasg
- Aarẹ Buhari ni wọn yoo lo asiko igbele yii lati fi ka aarun Coronavirus mọ igun gbogbo to ba lugọ si, lati fi mọ awọn to ti ni ajọṣepọ pẹlawọn eeyan to nii, ibi ti wọn farasinko si ati lati fi wọn sinu isera.
- Aarẹ wọn yoo tun fi asiko naa tọju awọn ti wọn ti fidi rẹ mulẹ pe wọn ni arun naa pẹlupẹlu ririi daju pe ko tan lọ sawọn ipinlẹ miran lorilẹede Naijiria.
- Ayẹwo finifini yoo maa wa fawọn ọkọ to ba n ko ounjẹ atohun elo itọju alaisan wọle sawọn ipinlẹ ti aṣẹ yii bawi.
- Awọn ibudokọ ojuomi ni ipinlẹ Eko yoo wa ni ṣiṣi.
- Ayẹwo finifini yoo maa wa fun awọn awakọ ati ọkọ to ba n ko awọn ẹru koṣemani kuro lawọn ibudokọ ojuomi naa.












