Coronavirus in Nigeria: Seyi Makinde fojú hàn n'íta fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn tó ṣẹ́gun Coronavirus

Gomina ipinle Oyo, Seyi Makinde

Gomina ipinlẹ Oyo, Ṣeyi Makinde foju han n'ita gbangba fun igba akọkọ lẹyin ti o jaja ṣẹgun aarun Coronavirus.Makinde ṣe abẹwo si ibudo itọju awọn alaarun to n bẹ ni agbegbe Olodo niluu Ibadan lọsan ọjọ Aje.

Nibẹ lo ti ṣe ayewo awọn ohun elo igbalode ti ijọba ipinlẹ Ọyọ ra sibẹ lati dẹkun itankalẹ aarun Coronavirus.

Makinde jẹ ọkan lara awọn gomina mẹta to lugbadi aarun covid-19 ni Naijiria.

Gomina Makinde ni gomina keji ti yoo bo lọwọ aarun coronavirus lẹyin ti gomina ipinlẹ Bauchi, Bala Mohammed naa ti gbadun.

Seyi makinde

Nasir El-Rufai ni gomina kẹta to laarun covid-19 lorilẹede Naijiria.

Lẹ́yìn ò rẹyìn, Seyi Makinde bori arun Coronavirus

Iroyin ayọ fun gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ.

Gomina ipinlẹ naa, Onimọẹrọ Ṣeyi Makinde ni oun ti pada lọ ṣe ayẹwo ara oun lẹẹmeji ọtọọtọ lati mọ boyi arun Coronavirus ṣi wa lara oun tabi o ti lọ ati pe ayẹwo mejeeji bayii lo fihan pe ṣaka lara oun le.

Afikun nipa aarun Coronavirus
Coronavirus

Ni ọjọ aje to kọja ni Gomina Makinde gbee jade loju opo twitter rẹ pe ayẹwo ti fihan pe oun ni arun Coronavirus lara to si ṣe bẹẹ wọ igbele iyasọtọ lọ gẹgẹ bi ilana aatẹẹle ti awọn onimọ nipa kokoro arun ati ilera ṣe laa kalẹ fun un.

Ilakalẹ fun ayẹwo ẹni to ba ni arun yii ki o to lee gba iwe ṣaka lara da ni lati ṣe ayẹwo meji ọtọọtọ eyi ti yoo fihan pe ko ni arun naa mọ; mejeeji yii si ni Makinde ṣe bayii.

Seyi makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi makinde

Ninu ọrọ to fi si oju opo Twitter rẹ, Gomina Ṣeyi Makinde ni oun mọ riri adura atilẹyin ati adura awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ lasiko ti oun fi wa ni igbele iyasọtọ fun itọju arun naa.

O fi kun un pe oun yoo si pada si ẹnu iṣẹ ni ọjọ Aje.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, Kọmiṣọna fun eto iroyin ati itaniji, Ọgbẹni Wasiu Ọlatubọsun ṣalaye pe aay bẹ silẹ o bẹ are ni gomina Makinde fẹ fi ọrọ ipadabọ rẹ ṣe bayii pẹlu pipada si ẹnu iṣẹ lẹyẹ o ṣọka lati tẹsiwaju pẹlu eto gbogbo lati le arun Coronavirus wọgbẹ ni ipinlẹ Ọyọ.