Coronavirus in Nigeria: Ṣeyi Makinde ní àrùn Coronavirus kò leè borí òun àtará ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́

gomina ṣeyi makinde

Oríṣun àwòrán, oyo state government

Iroyin to ba ọpọ lẹjafuu ni iroyin 'Mo ti ni arun Coronavirus'eyi ti Gomina Seyi Makinde gbe jade ni ọjọ Aje loju opo twitter rẹ.

Nibayii ti o ti lo ọjọ meji ni igbele lẹyin ikede yii, gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde ti ṣalaye pe ko si nnkan ti Coronavirus yoo lee fi oun atawọn eeyan ipinlẹ Ọyọ to ni arun naa ṣe.

Makinde to ni oun dupẹ fun obitibiti ojo adura ti gbogbo eeyan n fi ṣọwọ si oun ṣalaye pe bẹmidije loun, ẹmi oun yii girigiri, eleyi to fi daju pe oun ati gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ ti ọrọ kan yoo lee ruu la.

Gomina Makinde wa rọ awọn eeyan ipinlẹ naa lati maa tẹle itọni ati ilakalẹ igbimọ amuṣẹya ti ijọba gbe kalẹ lati gbogun ti arun COVID-19 ni ipinlẹ Ọyọ lati lee tete kapa arun naa lọgan ni ipinlẹ ọhun.

Àkọlé fídíò, Coronavirus: Ṣé ọtí leè dènà tàbí pa àrùn Coronavirus bi?

Nibayii, eeyan mẹjọ lo ti ko arun Coronavirus ni ipinlẹ Ọyọ ninu eyi ti Gomina Seyi Makinde pẹlu wọn.

Bakan naa ni wọn ti tu eeyan kan silẹ lẹyin ti o gba iwosan lọwọ arun ọhun.