Kara bridge explosion: Àjọ Lasema sọ pé wọ́n rí òkú nínú èèrù iná tó jó nítòsí Berger

Awọn osiṣẹ panapana nibi iṣẹlẹ naa

Oríṣun àwòrán, lasema

Ajọ to n mojuto iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, Lasema, sọ pe oun ri oku ninu eeru ina awọn ọkọ agbepo to gbina lori afara Kara, nitosi Berger nilu Eko loru ọjọ Abamẹta.

Iroyin sọ pe awọn ọkọ to gbe epo bẹtiro ati gaasi ti isede ka mọ ori afara Kara nilu Eko gbina lẹyin ti ibugbamu kan waye.

Ni nkan bi aago mejila kọja ogun iṣẹju l'oru ọjọ Aiku, ogunjọ, oṣu Kẹfa ni iṣẹlẹ naa waye.

Ajọ Lasema sọ pe awọn oṣiṣẹ pana-pana ri ina naa pa lẹyin to jo ọkọ agbepo mẹrin, o si tun sọ pe iwakuwa ọkọ lo fa ijamba naa.

Ọkan lara awọn awakọ ọkọ ti ọkọ wọn jona, Yusuf Tiamiyu ti ọkọ rẹ gbe gaasi, sọ fun akọroyin BBC, Ajoke Ulohotse pe inu ọkọ ni oun wa nitori isede lasiko ti ijamba naa waye.

Ẹ gbọ ohun to sọ ninu fidio yii.

Àkọlé fídíò, Kara bridge fire: Ìséde ká mi mọ́ ọ̀nà ni mo ní kí n sùn, ki ọkọ̀ mi tó jóná

Tiamiyu sọ pe "mo n mura lati sun ninu ọkọ katakata (tractor) ti mo maa n sun si, ni ọkọ bẹtiro kan ti bureeki rẹ da kọ lati ṣiṣẹ kọlu ọkọ mi, ati ọkọ bẹtiro.

"Ti kii ba ṣe ti isede yii, ijamba yii ki ba ti waye, nitori pe owo kekere kọ lati padanu bayii."

Awakọ tọkọ to jona ni Kara

Oríṣun àwòrán, lasema

Gẹgẹ bi ajọ Lasema ṣe sọ, ọkọ agbepo kan to gbe epo bẹtiro ẹgbẹrun lọna mẹtalelọgbọn lita lo kọlu ọkọ agbepo miran loju ọna naa.

Awọn osiṣẹ panapana nibi iṣẹlẹ naa

Oríṣun àwòrán, lasema

Ikọlu naa si lo fa ina to jo.

Ṣugbọn ṣa, ajọ naa ko ti i sọ iye eeyan to ku ni pato.