2019 World Happiness: Ìwàdíì sọ pé ìdùnnú ti pọ si ní Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Atẹjade tuntun kan ti ajọ ajọ iṣọkan agbaye fi sita lori ayajọ ọjọ idunnu l'agbaye fihan pe orilẹede Naijiria ti sun kuro ni ipo kọkanlelaadọrun to wa ni ọdun 2018 si ipo kẹtadinlelọgọrin lọdun 2019, laarin awọn orilẹede ti inuwọn dun ju l'agbaye.
Abọ iwadii naa fihan pe idunnu ti pọ si ni Naijiria ju ti tẹlẹ lọ.
Abọ iwadi ajọ naa ṣe igbelewọn awọn orilẹede mẹrindinlọgọjọ lẹyin to ṣewadi awọn nkan bi i imọ ẹrọ, ihuwasi lawujọ, to fi mọ aawọ ati ipa ti awọn ilana iṣejọba ni lori bi inu awọn araalu ṣe n dun si.
Finland maintain dia number one position from last year as di happiest kontri for di world. Orilẹede Finland lo ṣi wa ni ipo kinni gẹgẹ bi orilẹede ti idunnu pọ si ju lọ laye.
Orisun: World Happiness Report 2018
Awọn orilẹede apa iwọ oorun ilẹ Afrika kan ko fi bẹ ẹ ṣe daada ninu igbelewọn naa. Cameroon wa ni ipo mẹrindinlọgọrun, Ghana wa ni ipo mejidinlọgọrun, Sierra Leone wa ni ipo mọkandinlaadoje, ti Liberia si wa ni ipo mọkanlelogoje.








