Afcon 2019: Super Eagles ti wa gba owó àjẹ́mọ́nú wọn báyìí

Awọn ọmọ ikọ agbabọọlu Naijiria ti gba owo ajẹmọnu wọn lẹyin ti wọn fi fi aidunu han lori ọrọ naa.
Agbẹnusọ NFF, Toyin Ibitoye lo sọ fun BBC Yoruba bẹẹ.
Ti ẹ ba ranti, igbakeji balogun ikọ̀ Super Eagles Ahmed Musa sọ sẹyin ni Alexandriar orilẹede egypt nibi ti idje ife ẹyẹ AFCON ti n waye.
O fidi rẹ mulẹ pe awọn ko tii ri awọn ajẹmọnu gba fun idije Afcon to n lọ lọwọ.
Musa fi aidunnu rẹ han si aṣa jíjẹ awọn agbabọọlu ni ajẹmọnu, eyi to wọ pọ laarin awọn ẹgbẹ agbabọọlu ilẹ Afrika, to si rọ awọn alaṣẹ ajọ to n mojuto bọọlu gbigba lati jawọ ninu iwa naa.
Musa ni bo tilẹ jẹ pe awọn ko ri ajẹmọnu gba, awọn ko ni i jẹ ki eyi da omi tutu si wọn l'ọkan. O ni awn yoo ṣe ojuṣe awọn si Naijiria bo ṣe tọ ati bo ṣe yẹ.
''Ikọ Super Eagles ti fi ẹnu ko lati gboju kuro lara ọ̀rọ̀ ajẹmọnu lasiko yii, bi ko ṣe ko gbaju mọ ọna lati gba ife ẹyẹ Afcon 2019.
Lori ohun to fa a ti Super Eagles ko fi bẹẹ ṣe daada lati igba ti idije naa ti bẹrẹ, Musa ni eyi ko ṣẹyin bi oorun to n mu ni ilu Alexandria ṣe ti l'agbara ju, ti ko si tii mọ awọn lara.
Ninu ọrọ tirẹ, olori akọnimọọgba Super Eagles, Gernot Rohr, sọ pe o da oun l'oju pe Naijiria ni anfaani lati gba ife. Ati pe awọn ọmọ ikọ Super Eagles yoo bẹrẹ si ni ṣe daada ju ti tẹlẹ lọ.
Bakan naa ni Rohr sọ pe oun yoo mu ayipada ba awọn ti oun yoo lo fun idije ti yoo waye pẹlu Madagascar l'ọjọ Aiku.
Akọnimọọgba ikọ̀ Madagascar, Nicholas Dupuis, sọ pe lootọ̀ ikọ̀ oun ni ko l'agbara pupọ laarin awọn ti wọn jọ wa ni isọri kan naa, ṣugbọn awọn yoo bori ni idije ọjọ Aiku.













