NGA VS GUI: Super Eagles àti Syli National Guinea ṣẹ́ eegun ẹ̀yìn Guinea pẹ̀lú 1-0

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ikọ agbabọọlu ọkunrin fun orileede Naijiria Super Eagles, wọ iya ija pẹlu akẹgbẹ wọn, syli Nationale lati orileede Guinea.
Ifẹsẹwọnṣẹ yii ni ẹlẹkeeji ti wọn yoo gba ninu idije Afcon 2019, lẹyin ti wọn jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn akọkọ pẹlu Burundi.
Kenneth Omeruo lo gba bọọlu kan ṣoṣo ti Naijiria fi bori sinu àwọ̀n nibi idije naa to waye ni papa iṣere Alexandria, nilu Alexandria.
Nibayii, Super Eagles ti bọ si ipele keji (Round of 16) idije Afcon 2019.








