AFCON 2019: Níbo ni ọ̀rọ̀ owó ajẹmọnu ikọ Super Eagles dé dúró?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Láìpẹ yìí ni ìròyìn tàn ká pé àwọn ọmọ ikọ Super Eagles n bínu pé afi dandan ki awọn aláṣẹ san owo ajẹmọnu awọn, ti wọ́n si dún koko pe ó ṣeeṣe ki awọn ma lọ si ibi ipade apero kan ti yoo sáju ifẹsẹwọnsẹ wọ́n pẹ̀lú Guinea láàná.
Sùgbọ̀n ẹyìn-ò-rẹ́yìn ìfẹsẹwọ́nsẹ Super Eagles pẹ̀lú Guinea eyí ti wọ̀n gbá àmi ayò kan si odo lẹ́yìn ti wọ́n sọ ọ̀pọ́ ànfani nu lóri pápá.
- Sọ àsọtẹ́lẹ̀ orílẹ̀èdè tí yóò borí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ t'òní
- Ẹyẹ ju ẹyẹ lọ, Super Eagles fi àmì ayò kan gbé ẹyẹ Swallow ti Burundi mì
- Panumọ́, yé parọ́, ₦15m ni Sẹ́nétọ̀ kan ń gbà lówó oṣù - Itsey Sagay sí Lawan
- Kí ló mú bàbá àti ọmọ rẹ̀ méjì rẹ́wọ̀n oṣù mẹ́fà he ?
- Àǹfàní wà láti fí ìwé ìrìnnà ránṣẹ́ ṣùgbọ́n àwọn èèyàn kò lòó ni -NIS

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nínú ìwádìí BBC láti mọ bóya àwọn ikọ̀ agbábọọlù Super Eagles ti gba owó ajẹmọnú wọ́n, BBC ò le fìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ bóyá wọ́n ti rí àwọn ajẹmọnu náà gbà sùgbọ́n àwọn ayọlo ti wọ́n sọ ko jẹ ki a le sọ pato ibi ti ọ̀rọ̀ dé. Sùgbọ́n ó jọ bi ẹni pe wọ́n ti ṣe ileri fún wọ́n pé wọ́n o rówó gbà ni ọjọ ẹtì ọ̀la yìí.
Ola Aina tó ń gbá fún ẹyìn apá òsì " Asoju awa ikọ Super Eagles ati igbákeji rl pè wá jọ, wan si ni e wó ẹ tẹti, sááju oun gbogbo isẹ́ ni awá ṣe nibi, iṣk ki a gbá bọ́ọ̀lù si ni, ẹ jẹ́ ki a ṣe ǹkan to yẹ ki a ṣe láti sojú orílẹ̀-èdè wa, láti sóju ara wa àti awọn ẹbi wa, sááju ohun gbogbo a ni iṣẹ́ láti ṣe ǹkan to gbé wa wá sibi nìyìí, ẹ jẹ ki a gbá bọọ́lù ki a si mú èsì gidi jáde.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀ Akọnumọọgba wọ́n Gernot Rohr" Ọ̀rọ̀ mí si àwọn olólùfẹ ikọ super Eagles ni pe ki jẹ ki awọn ọmọ agbábọọlu Nàìjíría ma wú wọ́n lóri, nítori wọ́n n sapa wọ̀n láti gbe ogo fún Nàìjíríà nínú ìdíje AFCON. wan fi ifẹ han nípa idije yìí ati àwọn ǹkan míran náà, eyi si jẹ iwúri fún gbogbo wa. John Mikel obi ní iṣẹ́ to pọ̀ láti ṣe nínú ìdíje tó lọ lọ́wọ́ yìí, ó ṣe wáhala púpọ̀ láàná nítori ó ba àwọn ìjọba sọ̀rọ̀ sùgbọ́n àwọn ọmọ ikọ rẹ̀ ló ṣe fún.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ní ti Alex Iwobi o ní " ẹ jẹ́ ki a fí iyẹn sí ẹ̀gbẹ́ kan (ọ̀rọ̀ lóri owó ajẹmọnu tó n dá wàhálà sílẹ̀)láàrin ara wa, sùgban ǹkan to ṣẹlẹ̀ ni pe ǹkan ti a ba ṣe lóri pápá lo ṣe pàtàkì jù, kó si ǹkan ti yóò gbe oju wa kúro láti ṣe aṣe ọri, inú gbogbo wá lo dùn








