Itsey Sagay: Irọ́ ni Ahmed Lawan pa pe ₦750,000 ni Sẹ́nétọ̀ kan nń gbà lóṣù

Oríṣun àwòrán, @Social_NG
Alaga fun igbimọ̀ oludaninimọran fun aarẹ Buhari lori iwa ajẹ́banu, Ọjọgbọn Itsay Sagay ti fesi pada lati tako ọrọ ti aarẹ ile asofin agba, Ahmed Lawan sọ pe ko si asofin agba to n fi apo sakasaka di owo lọ̀ sile.
Lasiko to n ba akọ̀royin sọ̀rọ̀, Sagay pa Lawan lẹ́nu mọ̀ pe ko dẹ́kun irọ̀ pipa, ko si ma si awọ̀n ọ̀mọ̀ Naijiria lọna, pẹlu afikun pe miliọnu mẹẹdogun naira ni asofin agba kọọkan n gba lowo osu.
Itse Sagay fikun pe irọ to jinna si ootọ ni ọrọ kan ti Lawan sọ pe ẹgbẹrun lọna ọtalelẹẹdẹgbẹrin o din mẹwa naira, (₦750,000) ni asofin kọọkan n mu ls sile losu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Agba amofin naa sọ pe awọn ọmọ Naijiria fẹ mọ iye ti asofin kọọkan n mu lọ sile losu, ko si yẹ ki ẹnikẹni maa fi ẹkọ tanna fun wọn.
Sagay fikun pe, irọ diẹ, ootọ diẹ ni Lawan sọ, nitori gbogbo aye lo ti mọ pe inu ajẹmọnu awọn asofin ni wọn di owo to lorukọ si.
"Ta ba wo, a lee ni ootọ ọrọ ni aarẹ ile asofin agba n sọ nipa owo osu awọn asofin agba naa, amọ eelo ni apapọ owo ti wọn n mu ls sile losu, o to miliọnu mẹẹdogun naira."









