King Millie: Mo mọ ọsàn hó ní ìyàwó mí ṣe bá mi ṣọrẹ ní kékeré, a sì padà fẹra

King Millie ati aya rẹ

Oríṣun àwòrán, @iKingMillie

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Yoruba ni ọrọ ifẹ, bii adanwo ni, bẹẹ si ni ifẹ ko mọ olowo abi talaka, bẹẹ ni ko mọ abuda ara.

Ibikibi ni afẹfẹ ifẹ ti le fẹ lu ẹda, bẹẹ si ni ọrọ ifẹ kọja agbara ẹda.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu ọkunrin ati obinrin kan ti wọn sẹsẹ se igbeyawo amọ ti wọn ti jẹ ọrẹ ati kekere.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n salaye bi ọba oke se mu se alabapade aya rẹ lati igba ewe loju opo Twitter rẹ, ọkunrin kan to n jẹ King Millie ni iyalẹnu lọrọ awọn.

King Millie ati aya rẹ pẹlu ẹlomiran

Oríṣun àwòrán, @iKingMillie

Millie ni ọsan ni oun n kiri lọ nigba ti oun wa ni kekere, ti oun si pada ọmọbinrin naa.

O ni obinrin yii lo se akiyesi pe oun mọ ọsan ho daadaa, to si joko ti oun, nibẹ si ni awọn ti di ọrẹ titi di oni.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

"Loni, inu mi dun pupọ pe mo fẹ ọrẹ mi lati igba ewe."

King Millie ati aya rẹ

Oríṣun àwòrán, @iKingMillie

Alaye ọkunrin yii lo mu ki ọpọ eeyan maa ki ku oriire pe, o ba obinrin bii ọkan rẹ pade.

Koda, ẹnikan ni kii ṣe gbogbo obinrin lo le duro lati lo ifẹ pẹlu ọmọ ọlọsan lasan lasan, dipo bẹẹ, wọn yoo maa le awọn eeyan to n lo ọkọ ofurufu kiri ni.