Tortoise surgery: Àwọn dókítà fi wákàtí mẹ́fà ṣiṣẹ́ abẹ dóòlà ẹ̀mí ìjàpá tí ọkọ̀ gbá

Ijapa atawọn dokita to n sisẹ abẹ fun

Oríṣun àwòrán, Others

Dokita kan to jẹ onimọ nipa itọju ẹranko, Nura Abubakar to n ṣiṣẹ nile iwosan itọju ẹranko nipinlẹ Sokoto, ti ṣalaye ni kikun bi iṣẹ abẹ ti wọn ṣe fun ijapa ti ọkọ kan tẹ, ti igba ẹyin rẹ si fọ, ṣe lọ.

Dokita Abubakar sọ fun BBC pe, ọmọ ẹni to ni ijapa ọhun, Sadiq Sulaiman n fẹyin rin pẹlu ọkọ, lo fi ṣeeṣi gun ijapa naa lori, eyi to mu ki igba ẹyin rẹ fọ.

O ṣalaye pe kete ti ijamba ọhun ṣẹlẹ ni ọkunrin to ni alabahun naa gbe digba-digba lọ si ile iwosan kan niluu Argungu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣugbọn nigba ti apa ile iwosan Argungu ko kaa mọ ọ, ni olowo ijapa yii to fẹran ẹranko gbe e lọ sí Sokoto, nibi ti wọn ti ṣiṣẹ abẹ fun un.

Ij

Oríṣun àwòrán, Other

Dokita Abubakar ni, awọn dokita onimọ nipa itọju ẹranko mẹfa lo jọ ṣiṣẹ abẹ naa, o ni ohun to jẹ idunnu oun ni pe, ijapa naa ti gbadun bayii, o si ti n ṣere nile olowo rẹ.

"Ohun akọkọ ti a ṣe ni lati fun ijapa naa ni itọju ni kiakia, eyi to jẹ ki ara rẹ balẹ di ọjọ keji nitori o ni ipalara to pọ gan an ninu ijamba to ṣe e,"

Ẹwẹ, Sulaiman to ṣeesi fi ọkọ tẹ ijapa baba rẹ mọlẹ, wa fi idunnu rẹ han si bi iṣẹ abẹ ti wọn ṣe fun ẹranko naa ṣe yọri si rere.

Ijapa tawọn dokita sisẹ abẹ fun

Oríṣun àwòrán, Other

O ni ẹri ọkan oun ko ba ti jẹ ki oun gbadun, to ba jẹ pe ijapa naa ko ru u la ni.

Fọto ijapa ọhun ti kọkọ lu ori ayelujara pa, lẹyin ijamba ọkọ to ṣẹlẹ si i.