Ni Jigawa, àwọn obìnrin dáwó ra ọkọ̀ N1m láti máa fi gbé aláboyún ní iletò kan

Awọn obinrin kan ni ileto Bordo ni ipinlẹ Jigawa, ti da owo jọ fi ra ọkọ ti wọn fẹ maa fi gbe awọn alaboyun lọ sileewosan lasiko isẹlẹ pajawiri.
Awọn obinrin ileto naa ni awon da owo naa, lati lee dẹkuun ipenija ati iṣoro to rọ mọ gbigbe awọn alaboyun lọ si ileewosan, eyi to n koju wọn.
Lati ileto Bordo de ileto to sun mọ ọ ju jẹ kilomita mọkandilọgbọn, yatọ si pe ileto naa da wa, ọna to so o pọ mọ ibi ti ileewosan naa wa ko dara rara.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn rèé nípa bí Ogbomoso ṣe pa ọba, yọ nǹkan ọkùnrin rẹ jó kiri ìlú
- Alámì ẹ̀yẹ Scrabble Paul Sodje àti ọ̀rẹ́ rẹ́ kú lásìkò tó fẹ́ lọ́ sanwó ìdóòlà ẹ̀mí àbúrò rẹ̀, tí afurasí darandaran jí gbé
- Ìjàmbá iná míràn tún wáyé ní pápákọ̀ ojú omi Beirut
- Ẹ fi dókítà àgùnbánirọ̀ rọ́pò àwọn dókítà tó ń yanṣẹ́ lódì - Ìjọba àpapọ̀ pàṣẹ
- Afenifere fara ya lórí bí Tinubu ṣe jókòó kí Ooni
- Háà ilẹ̀ wẹ! ọ̀dọ́ 47,000 fẹ́ di Amotekun, agbófinró yẹ̀ wọ́n wò yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́
- Aáwọ̀ oyè PDP gbé Fayose àti Seyi Makinde kọlu ara wọn, ìjà ń bọ̀
Arabinrin Halima Adamu to lewaju igbesẹ naa ṣalaye fun BBC pe, wọn bẹrẹ pẹlu eto ẹdawo laarin ọkọọkan awọn obinrin ni ileto naa.

O ni ẹgbẹrun kan Naira ni obinrin kọọkan labule naa fi bẹrẹ ẹdawo ọhun loṣooṣu.
O ni eyi ni awọn da titi ti owo naa fi wọ miliọnu kan Naira, ti wọn lo ra ọkọ naa.
Adamu fi kun un pe ni bayii, ko si igbakugba ti awon ko lanfani lati maa gbe alaboyun to ba fẹ rọbi tabi ni iṣẹlẹ pajawiri.
O ni nigbakugba ti alaboyun ba ti nilo lati sare lọ fun ilera pipe, ẹgbẹrun meji naira pere ni ọkọ rẹ yoo san, ninu eyi ti won yoo ti yọ ẹgbẹrun kan ati ẹẹdẹgbẹta Naira fi ra epo sinu oko .
Obinrin naa ni wọn yoo si mu ẹẹdẹgbẹta naira to ku pamọ fun itọju ọkọ tori ọjọ iwaju.
O tun sọ siwaju sii pe, ọpọ igba l'awọn alaboyun naa maa n bimọ loju ọna.
Olori ileto Bordo, Alhassan Haruna fi to BBC leti pe, pẹlu bi ọkọ naa ṣe wa fun ríran awọn alaboyun lọwọ, sibẹ opopona ko dara.
O ni ọpọlọpọ awon obinrin naa ni yoo ti bimọ, ki wọn to de ileewosan.
O wa rọ ijọba lati seranwọ lori atunse ọna naa.
Amọṣa, akọwe ajọ eleto ilera alabọde ni ipinlẹ Jigawa, Dokita Kabir Ibrahim salaye pe, o ti le ni ọgọfa ọkọ ti wọn ni kaakiri ọkan o j'ọkan awọn ileto nibẹ.
Bẹẹ si ni bii ọgọrun lo ti bajẹ ninu wọn.














