2019 Guber election: Adelabu pe Makinde, INEC l'ẹ́jọ́

Adelabu àti Makinde
Àkọlé àwòrán, 2019 Guber election: Mí ò faramọ èsi ìdìbò tó gbé Makinde wolé

Olóye Adebayo Adelabu to jẹ olùdíje lábẹ̀ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Party (APC) ní ìpínlẹ̀ Oyo ti fi ìwé ẹsun sọwọ si ilé ẹjo tó ń gbọ ẹsun ìdìbò láti pe ìjáwe olúbori ọgbẹni Seyi Makinde ti ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party (PDP) lẹ́jọ nibi ìdìbò tọ wáye lọ́jọ́ kẹsàn oṣù kẹta.

Onímọ̀ ẹ̀rọ Makinde ní àjọ elétò ìdìbò INEC kéde pe ó jáwé olúbori nínu ìdìbọ gomins tó wáye lọ́jọ́ kẹsàn oṣù kẹta lkyìn to ní ìbò ẹgbẹ̀run lọ́nà ẹẹdẹgbẹ́ta o lé ti Adelabu si ní ẹgbẹ̀run lana ọ̀ọ̀dúnrún lé díẹ̀

Àkọlé fídíò, Ojojúmọ ní mọ ń kẹ́kọ̀ọ́ lára ọmọ mi to jẹ akanda
Àkọlé fídíò, Okùnrin SARS náà sọ pé òun máa pa èèyàn síbi ni- Aladugbo

Awọn to wà nínú ìgbẹ́jọ yìí ni ẹgbẹ́ òṣèlú PDP àti àjọ elétò ìdìbò INECBákan náà ní lóri ìdìbò ilé igbìmọ aṣòfin àgbà àti ilé ìgbìmọ ìpínlẹ̀, ilé ẹjọ tó ń ri si ìgbẹjọ ìdìbò gba ìwé ẹsun mọkanlélọgbọ̀n.

Iwé ẹ̀sun mẹ́rìn ló wọlé fun ti ilé ìgbìmọ aṣòfin àgbà, mẹ́jìla ní ti ilé ìgbìmọ àsṣojú sòfin nígbà ti mẹ́ẹ̀dógún jẹ ti ilé ìgbìmọ aṣòfin ti ìpínlẹ̀

Lẹ́yìn ọjọ mọkanlélógun tí wọn ba ti kédé ẹni to jáwe olúbori ni òfin fi lélẹ pe kí ẹni ti èsì ìdìbò kò ba tẹ́lọ́run kó kọ ìwé ẹsun rànṣẹ́, ìròyìn fi yé ni pe ọjọ kọkanlélọgbọ̀n oṣù kẹta ni ó pe ni ọjọ pé.