9ice: Tí ẹ̀mí bá sọ fún ẹ pé kò sí ǹkankan nínú orin mọ́, kò ní wù ẹ kọ

Àkọlé fídíò, Ìbànújẹ́ ló pọ̀ nínú òṣèlú Nàìjíríà tórí a ti lo Pásítọ̀, Wòlìí, Ọ̀jọ̀gbọ́n

Nigba ti 9ice dahun ibeere lori irufẹ adari to yẹ ki orilẹede Naijiria ni, o gbẹnu tan.

O ni ko sohun to n wu ni lori ninu oṣelu Naijiria pẹlu bo ṣe n lọ lọwọ lọwọ paapaa pẹlu iru awọn adari to ti jẹ.

Abolore ni "ẹni to ku ti Naijiria nilo bayii ni ẹni to ni erongba to si nibẹru ọlọrun"

O tẹnu mọ ọ pe ẹni ti yoo pin owo ilu ati mudunmudun ijọba dọgba lo yẹ ko dari orilẹede Naijiria.

Bakan naa, Abolore gboriyin fun awọn agba olorin to jẹ aṣaaju wọn to si ni iṣẹ awọn, iṣẹ ẹmi ni tori ẹmi lo n dari ohun gbogbo yala bi waa ba tẹsiwaju gẹgẹ bi olorin ni tabi bẹẹ kọ.