Viral Diarrhea: Òjò ló lè mú kí ìtànkálẹ̀ àrun ìgbẹ́ ọ̀rìn má tètè dópin ni Eko- Iléeṣẹ́ ìlera

abẹrẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Arun igbẹ ọrin yii bẹ silẹ laipẹ ni ipinlẹ Eko ni eyi ti wọn ni Oluwa ti n gbakoso

Ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Eko to n mojuto eto ilera ni ẹni mọkanla lo ti ba arun igbẹ ọrin to n tankale yii rin.

Arun itankalẹ igbẹ ọrin yii lo waye lataari inu didaru fawọn eeyan ni ipinlẹ Eko ni guusu Naijiria.

Ileeṣẹ ilera ni ipinle Eko ṣalaye fun BBC pe o le ni iṣẹlẹ aadọrin le ni ọọdunrun to ti ṣẹlẹ bayii.

Tunbosun Ogunbanwo to jẹ adari ẹka imọsilara awọn ara ilu ni ileeṣẹ ijọba to n mojuto ilera ni Eko fidiẹ mulẹ pe eniyan mọkanla lo ti doloogbe lataari arun yii.

Tunbosun salaye pe, agbara ijọba ti n ka itankalẹ arun yii ati pe ki awọn eniyan ipinlẹ Eko lọ fọkan balẹ.

Àkọlé fídíò, Fanny gbà kádàrá lórí àwọn orin rẹ̀ kí wọn to ṣe alakọkọ lọdun 2012

Arun igbẹ ọrin yii maa n pa eniyan ti ko ba tete ri itọju to peye lẹyin ti inu rẹ ba ti n daru.

Àkọlé fídíò, È gbọ òun ti ojú awọn ara ipinle Ogun rí lọwọ ìṣẹlẹ omiyale

Ileeṣẹ ijọba yii ni arọọrọda ojo to n rọ ati wahala omiyale to n ṣẹlẹ ni ipinlẹ Eko lo tun jẹ ki arun naa tete tankalẹ sii.

Tunbọsun mẹnuba iwa ibajẹ ki awọn eniyan maa ya igbẹ tabi ṣe igbọnsẹ sinu odo ati inu agbara ni eyi to n ran itankalẹ arun lọwọ bayii.

Àkọlé fídíò, Omiyalé Àkútè: N50 si N100 làwọn èèyàn fi ń kọjá lórí ẹ̀kún omi l‘Ákútè

Agbẹnusọ ẹka eto ilera ni ipinlẹ Eko tun mẹnuba awọn ile kan ti ko si ile igbọnsẹ nibẹ tabi ti awọn eniyan kii lo lawọn adugbo kan ni ipinlẹ Eko ni eyi to n jẹ ki arun naa tan sii paapaa ojo to ṣi n rọ bayii.

Àkọlé fídíò, Omiyale Ile Ife: Dukia sọfọ, awọn eniyan si tun farapa

Bayii, ikilọ pataki ni ileeṣẹ eto ilera ti ipinlẹ Eko n kilọ bayii ni pe oju ni alakan fi n ṣọri.

omo

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Itọju lasiko ni kete too ba ti kẹfin arun yii ṣe koko

Imọtoto lo le ṣegun awọn arun gbogbo ati pe ki onikaluku tọju ayika rẹ.

Wọn tun kilọ pe kawọn olugbe ipinle Eko sa fun omi mimu ati ohun jijẹ koda eso ti ko ba mọ nitori pe ilera ni ọrọ.

Àkọlé fídíò, Chef Adefunkẹ: Òórùn ewé tí wọ́n n pọ́n ìrẹsì ọ̀fadà si jẹ́ adùn lọ́tọ̀

Ọdun 1985 ni iṣẹlẹ arun gastroeniteritis to n tankalẹ nipinlẹ Eko yii kọkọ ṣẹlẹ ni orilẹ-ede Naijiria.

Diẹ lara awọn ami arun igbẹ ọrin to n tankalẹ yii ni igbẹ gbuuru, inu rirun, eebi bibi ati iba ti ara ko gbona pupọju.

Itọju nile iwosan ni kete too ba ti kẹfin pe o fẹ ni arun yii ṣe pataki pupọ ni ayika rẹ.

Àkọlé fídíò, Ìbànújẹ́ ló pọ̀ nínú òṣèlú Nàìjíríà tórí a ti lo Pásítọ̀, Wòlìí, Ọ̀jọ̀gbọ́n