Flooding: Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ṣòfò, tí dúkìá àìmoye mílíọ̀nú naira sì bá ẹ̀kún omi lọ

Oríṣun àwòrán, Twitter/RovingReporter
Ọjọ buruku Eṣu gbomi mu ni ọjọ Abamẹta, ọjọ Kejila oṣu Kẹwaa jẹ fun ọpọ olugbe ilu Eko atawọn ilu miran nilẹ Yoruba nigba ti arọọrọda ojo di omiyale, agbara ya ṣọọbu.
Ọpọ eeyan lo gbemi mi nigba tile wo lewọn lori, bakan naa lomi ba ọpọ dukia jẹ.
Kaakiri ilu Eko ati lawọn ipinlẹ mii lapa iwọ oorun Naijria ni arọọrọda ojo ti ṣọṣe yala nipa ẹkun omi, ile wiwo tabi afara to ja.
- Kìí ṣé òjò àrọ̀rọ̀ọ̀dá nìkan, ọkọ̀ aképo tó dànù náà fà súnkẹrẹ-fàkẹrẹ l'Eko
- Omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù, ilé mẹ́ta wó, èèyàn mẹ́rin kú l'Eko
- Wo pàtàkì ayájọ́ ‘Má wọ kọ́mú’ tó kò lónìí
- Bílíọ̀nù mẹ́sàn án náírà ni ìjọba yóò ná lórí ẹ̀rọ amúnáwá lọ́dún 2020
- Odunlade fijó bẹ́ẹ, Lizzy padà sọ́dún 2012, Toyin Abraham tọ̀ lẹ́ẹ̀mẹwàá
- Super Eagles ṣetán láti gbéná wojú Brazil- Gernot Rohr
N ṣe lawọn eeyan fi aworan ijamba ti arọọrọda ojo naa ṣe ati bi oju popo ti kun fun omi, paapa julọ niluu Eko sori ayelujara. Diẹ ninu irufẹ aworan ọhun niyii.
Aworan yii ṣafihan ile to dawo lagbegbe Ita Ẹlẹwa ati Agric ni Ikorodu nipinlẹ Eko.
A gbọ pe ko si eeyan kankan to ba iṣẹlẹ mejeeji yi lọ ni Ikorodu.

Oríṣun àwòrán, lasema
Eeyan mẹrin lo padanu ẹmi wọn lẹyin ti ile kan wo ladugbo Magodo Iseheri lasiko, arọọrọda ojo Satide.
Ninu awọn mẹrin to ku naa la ti ri abiyamọ kan ati awọn ọmọ rẹ mẹta

Oríṣun àwòrán, rrslagos
Opopona Marosẹ ni Lekki nipinlẹ Eko ti wọn ngba pe o jẹ adugbo awọn to ri jajẹ diẹ ni omi ti ya wọ bayii.
Ẹkun omi naa ṣe idiwọ fun ọkọ lati lọ geregee, bakan naa lo ba ọpọ dukia jẹ.


Adugbo Razak Eletu ni Osapa Garden Estate ni Lekki lo sọ gbogbo olugbe ibẹ di konile-o-gbele lasiko yii.

Awọn eeyan ijọba ibilẹ Waterside rawọ ẹbẹ si Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun lẹyin ti ẹkun omi ọjọ Satide gba ọna to lọ si ijọba ibilẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Olufowobi Kenny

Oríṣun àwòrán, Facebook/Olufowobi Kenny
Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq lo fi aworan ẹkun omi ni ilu Ilorin sori oju opo Twitter rẹ, nibi to ti sọ pe awọn to da ilẹ sinu kọta lo n fa omiyale.

Oríṣun àwòrán, Twitter/Abdulrahman Abdulrazaq
Ẹkun ojo ṣe bẹbẹ nipinlẹ Ondo bakan naa, koda ọkọ oju omi lawọn kan n ba wọle wọn lẹyin ti omi ti gba iwaju ile wọn tan.

Oríṣun àwòrán, Twitter/RovingReporter

Oríṣun àwòrán, Twitter/Ibromicah












