Báwo ni Nàìjíríà ṣe gboyè orílẹ̀èdè tí ìtànkálẹ̀ òtútù ìgbá àyà tí pọ̀ jù lọ?

Oríṣun àwòrán, AFP
Ajọ to n mojuto eto ẹkọ awọn ọmọde lagbaye ti sọ pe orileede Naijiria ni ọwọja otutu igba aya ti peleke ju lọ lagbaye.
Ninu iwadi kan ti wọn ṣẹṣẹ gbe jade, ajọ naa to jẹ ẹka ajọ iṣọkan agbaye ṣalaye pe ida mọkandinlogun iye iku ọmọde ni Naijiria lọdun 2018 lo tatara otutu igba aya wa.
Ajọ ọhun tẹsiwaju pe ohun to saba ma n fa aisan yii ni aijẹun daada, eefin latara eedu ti wọn fi n dana ninu ile to fi mọ fifa atẹgun buruku simu layika.
Aisan otutu igba aya yii a maa ṣakoba fun ẹdọ foro ti ọyun a si maa ko si inu rẹ.
Ninu iwaadi ti wọn gbe jade, lagbaye lọdun 2018, otutu igba aya pa ọmọ tọjọ ori wọn ko to ọdun marun un to le ni 800,000.
Lara awọn ọmọ to ba aisan yii lọ la ti ri o kere tan ọmọ Naijiria 162,000 to tunmọ si pe ọmọ 443 lo n ku lojumọ kan ti mejidinlogun a si maa ba aisan yii lọ ni wakati kọọkan.

Oríṣun àwòrán, AFP
Ninu ọrọ adele aṣoju ajọ Unicef ni Naijiria, Pernille Ironside, o sọ pe ''aisan to le la ẹmi lọ ni otutu igba aya jẹ ti o si ti mu ọpọ ẹmi awọn ọmọde lọ ni Naijiria toun ti pe o ṣe dena.''
O fikun ọrọ rẹ pe pupọ awọn ileeṣẹ ati ẹka to n mojuto ilera lo ti gbagbe nipa rẹ ṣugbọn asiko to bayi lati mu ayipada wa''
Yatọ si orileede Naijiria awọn orileede mẹrin miiran ni itankalẹ aisan yi ti pakasọ.
Awọn orileede naa ni India, Pakistan, DR Congo ati Ethiopia.













