Ondo Kidnap: Ìyá ọmọ tí wọn jí gbé wà nílé iwòsàn tí wọn ń fa omi sí lára

Eniola Gold ati awọn obi rẹ

Oríṣun àwòrán, Eniola Gold

Ninu ẹkun asundakẹ ni ikọ iroyin BBC Yoruba ba Iya Eniola Gold, ọmọ to di awati lojiji ninu ile ijọsin kan ni ilu Akure, ti i se olu Olu Ipinle Ondo lọjọ isinmi.

Nigba ti Iya ọmọ naa n salaye bi ọrọ ti rin, o ni, ko ju bii ọgbọn isẹju si igba ti oun se abẹwo si Eniola ninu Ile ijosin awon ọmọde ti ẹka ijọ naa, to fi di awati.

Iya Ẹniola naa tẹsiwaju pe, titi diỌjọru, ko tii si igbesẹ kan pato ti awọn Ọlọpaa se si isẹlẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n sọ bi isẹlẹ ọhun ti ka lara to, baba Eniola ni orisirisi ipe lo n wọle sori ẹrọ ibanisọrọ oun wipe, ti awọn ko ba jawọ ninu wiwa ọmọ naa, o seese ki ẹmi oun ati iya rẹ gan lọ si.

Gold Eniola

Oríṣun àwòrán, Gold Eniola

Bayii, ninu hilahilo ni awọn obi ọmọ naa wa, ti awọn onisegun oyinbo si n fa omi si iya ọmọ naa lara ni ile iwosan kan ni ilu Ondo.

Ikọ iroyin BBC Yoruba tun kan si olu ile isẹ ọlọpaa to wa ni ilu Akure, lati fi ọrọ wa wọn lẹnu wo lori ibi ti wọn ba isẹ de lori isẹlẹ naa.

Eniola Gold ati awọn obi rẹ

Oríṣun àwòrán, Eniola Gold

Asoju fun alukoro Olopaa nipinle Ondo, Funmi J. F salaye pe, iwadii n lọ lọwọ lori bi Ẹniola ti se di awati ati pe, ileesẹ ọlọpa naa yoo se iwadii to ye kooro, ki won to sọ ohunkoun lori ọrọ naa.

Titi di igba ti a nko iroyin yii jọ, igbiyanju lati ba olori ijọ ti ọmọ naa ti sọnu, ijọ Sọ titobi rẹ, sọrọ lo ja si pabo, ti ko si gbe ẹrọ ibanisọrọ rẹ.