Honourable SOB Agunbiade: Ọ̀tọ̀ ni "Palliatives" ìjọba, ọ̀tọ̀ ni ǹkan ìní tèmi náà tí wọ́n jí kó
Ọmọ ile aṣojuṣofin to n ṣoju ẹkun idibo Ikorodu nile igbimọ aṣojuṣofin ipinlẹ Eko kan ti iroyin tan kalẹ pe o fẹ fi awọn nkan iranwọ Covid-19 ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi rẹ iyẹn Họnọrebu SOB Agunbiade ti ni irọ patpata ni iroyin naa to tan ka gbogbo agbaye.
Iroyin ọhun sọ pe lakoko ti awọn janduku bẹrẹ si ni lọ ji nkan ko nile awọn oloṣelu atawọn eekan lawujọ, wọn yabo ile SOB wọn si ko awọn nkan iranwọ Covid-19 to wa nibẹ.
Lẹyin eyi ni esi kan jade pe Họnọrebu ọhun ni awọn nkan ti wọn ji ko nile oun ni oun fẹ pin fun awn araalu lọjọ ibi rẹ eyi to jẹ ọjọ kẹẹdọgbọn oṣu kẹwa ọdun 2020.
Nigba to n ba BBC Yoruba sọ̀rọ̀, SOB Agunbiade ni ohun tawọn eeyan n pin kaakiri gẹgẹ bi iroyin yii jẹ amọọmṣe awọn kan lati gbẹ́ oun lẹsẹ gẹgẹ bi oloṣelu ni.
- Ẹ má gbìyànjú láti bo àṣírí ìpànìyàn tó wáyé ní Lekki, á ní ẹ̀rí tó dájú - Amnesty International
- Báyìí ni 50 Kobo ṣe dá ìfẹ̀hónú "Ali Must go" sílẹ̀ tó mú ọ̀pọ̀ ẹ̀mí akẹ́kọ̀ọ́ lọ
- Ìjọba ìpińlẹ̀ Eko ti kédé ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní gbogbo iléèwé aládàni àti ìjọba
- Aago mẹ́fà òwúrọ̀ sí mẹ́jọ alẹ́ ni ọ̀kadà yóò láǹfàní láti máa ṣiṣẹ́ ní Osun - Gómìnà Oyetola
- Àkùkọ dojú ìjà kọ ọlọ́pàá, ikú ló já sí fún agbófinró

Oríṣun àwòrán, SOB Agunbiade
"Mo ti pinu lati bii oṣu diẹ ṣaaju ọjọ mi pe mi o ni ṣe ayẹyẹ tabi apejẹ kankan ju ki n pin nkan fawn araalu lọ bii ounjẹ ti wọn o tii ṣe".
Agunbiade ni "owo ara mi ni mo lọ fi ra awọn nkan jijẹ ti mo fẹ pin, ọtọ ni awọn nkan iranwọ ti ijọba ipinlẹ Eko si ti lẹ orukọ mọ gbogbo nkan to jẹ iranwọ Covid-19".
"Kii ṣe ile mi ni wọn ti ji awọn nkan ti wọn pe ni "Palliatives" ko, awọn nkan ini temi ni wọn ko nile mi, ibajẹ si ni wọn fẹ fi ṣe si mi".
Họnọrebu Agunbiade kẹnu bọ ọrọ ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu BBC Yoruba lati ṣalaye oun to ni awọn eeyan gba sodi nipa oun.














