Trump picture: ọjọ́ tí Trump kí mi kú iṣẹ́ lórí 'twitter' ní inú mi dùn jù- Oyedele

Àkọlé fídíò, Trump picture: ọjọ́ tí Trump kí mi kú iṣẹ́ lórí 'twitter' ní inú mi dùn jù- Oyedele

Lati kekere ni mo ti n fi kalamu dárà nipa aworan yiya- Adedokun Oyedele

Ori lo kuku mọ iṣẹ aṣela ni awọn agba maa n wi nilẹ Oodua.

Adedokun Oyedele ni ọdọmọde lati ilu Oṣogbon ni ipinlẹ Osun to n fi kalamu ikọwe ti ọpọ n pe ni 'Biro'dárà nipa fifi ya aworan.

Lọdun 2019 ni Adedokun fi biro ya aworan aarẹ ilẹ America, Donald Trump ni eyi ti ayelujara baa polowo di nlaMọ̀ síi nípa Oyedele Adedokun tó ya àwòràn Donald Trump tó lu ayélujára pa.

Aworan yii de ọdọ Trump to si ki Adedokun ku iṣẹ ọpọlọ lati America.

Adedokun ni ko ya ẹbi oun lẹnu rara pe oun gbe iṣẹ fifi biro da ara nla lasiko yii nitori pe lati kekere ni oun ti maa n ya gbogbo wọn.

Bakan naa ni Oyedele ṣalaye kikun nipa irin ajo aye rẹ fun BBC pé kekere kọ ni ike Ramọ ni o.

Adedokun rọ awọn ọdọ ẹgbẹ rẹ pe ki wọn ma bẹru ijakulẹ nitori pe ọjọ ti a ba gun kọ ni an kan ọrun.