Obadiah Mailafia: DSS ti fi igbákejì gómìnà CBN tó ní gómìnà kan ní Àríwá Naijiria ní Ọ̀gá Boko Haram sílẹ̀

Obadiah Mailafia

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/OBADIAH MAILAFIA

Igbakeji Gomina Banki Apapọ Naijiria (CBN) tẹlẹri, Obadiah Mailafia ti ni oun ko mọ wi pe wọn ka ohun oun silẹ lasiko ti oun ṣe ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ileeṣẹ redio.

Mailafia sọ eyi lasiko to n ba BBC sọrọ lẹyin ti Ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS fi silẹ lẹyin ifọrọwanilẹnuwo.

O ni awọn Fulani meji ni wọn ri oun ti wọn si bẹrẹ si sọ gbogbo ohun to n ṣẹlẹ ninu ikọ Boko Haram fun oun nitori oun gbọ ede ti wọn n sọ.

Igbakeji Gomina Banki Apapọ Naijiria (CBN) tẹlẹri, Obadiah Mailafia ni ajọ DSS ko kan an nipa fun oun lati sọ ohun ti oju oun kori.

Mailafia fikun pe awọn oṣiṣẹ ajọ DSS wuwa ọmọluwabi si oun, ti wọn ko si fi iya jẹ oun lasiko ifọrọwanilẹnuwo naa.

Bakan naa ni Mailafia ni oun fẹran Aarẹ Buhari ati wi pe oun ṣe agbatẹru fun un, amọ awọn to wa ni iṣejọba rẹ ko fun aarẹ ni atilẹyin to nilo lati mu idagbasoke ba orilẹede Naijiria.

DSS ti fi igbákejì gómìnà CBN tó ní gómìnà kan ní Àríwá Naijiria ní Ọ̀gá Boko Haram silẹ

Ileeṣẹ otẹlẹmuyẹ lorilẹede Naijiria, DSS ti fi silẹ lẹyin ẹsun to fi kan gomina kan ni ẹkun ariwa Naijiria.

Obadiah Mailafia lo sọ lori redio pe gomina ni ẹkun ariwa Naijiria gan an ni ọkan gboogi lara awọn adari ikọ agbesunmọmi Boko Haram ni Naijiria.

O ni awọn ikọ Boko Haram to ti fẹhinti lo tu asiri naa si oun lọwọ.

Ilẹẹṣẹ DSS gbe e lẹyin ti iroyin naa kaakiri ayelujara ti wọn si fi ọrọ wa a lẹnu wo.

Obadiah wọ ọgba DSS lọ lati lọ wi ti ẹnu rẹ pẹlu awọn agbẹjọro rẹ meji ti orukọ wọn n jẹ Pius Akubo (SAN) ati Yakubu Bawa.

Amọ, lẹyin wakati mẹfa ni wọn fi silẹ, ti awọn ikọ afẹhọnuhan to jẹ alatilẹyin rẹ ko si kuro nibẹ titi ti wọn fi fi silẹ.

Àkọlé fídíò, Victor Agunbiade ni ojú àlá ni Ọlọrun ti yan iṣẹ́ ọmọ ogun ojú omi fún òun ní America