Pastor Chris Oyakhilome Rapture Maths: Àlùfáà ìjọ Christ Embassy ṣe ìṣirò ìgbà tí Jesu yóò dé

Pastor Chris Oyakhilome

Oríṣun àwòrán, Screenshot/Loveworld

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oludasilẹ ijọ Loveworld Ministries ti ọpọ mọ si Christ Embassy, Pasitọ Chris Oyakhilome ti ṣalaye bi o ti ṣeeṣe ki ipe dun ti opin aye yoo si de.

Pasitọ Oyakhilome sọ pe gbogbo eeyan ni lati wa ni imura silẹ nitori akoko naa ti sun mọle.

Pasitọ Christ Embassy nigba to waasu ni ṣọọṣi rẹ ṣalaye fawọn ọmọ ijọ rẹ pẹlu ẹkọ iṣiro lorii iye igba to ku ti igbasoke yoo fi de ati idi ti wọn fi gbọdọ mura silẹ.

"To ba jẹ pe ẹgbẹrun mẹta ọdun ni Jesu yoo lo ko to pada ni, a jẹ wi pe ẹgbẹrun un kan ọdun lo ku bayii ti yoo fi pada nitori o ti le lẹgbẹrun ọdun meji bayii ti Jesu ti pada lọ si ọrun".

Pasitọ Chris tun ni ''ṣugbọn bawo ni akoko naa ti sun mọ si, ẹ jẹ ki n ṣalaye rẹ fun yin lẹkunrẹrẹ.''

Alufaa Oyakhilome sọ pe igbasoke gan an ko ni apẹẹrẹ kankan ṣugbọn o le ṣẹlẹ nigba kugba.

Pasitọ ijọ Christ Embassy yaworan sori patako lati ṣe iṣiro bi iṣẹlẹ igbasoke naa ti le ṣẹlẹ.

Pasitọ Chris Oyakhilome

Oríṣun àwòrán, Facebook/Christ Embassy

Ninu aworan naa, o sọ nipa akoko ti Jesu kuro ninu tẹmpili lọdun 30AD ati igba ti wọn bi i laarin ọdun 4BC si ọdun 2BC lati fi mọ igba ti ipe yoo dun.

Oyakhilome ni ''ti a ba wo o lati ọdun 30AD, ki a wo ẹgbẹrun ọdun meji lati igba naa, ọdun 2030 tii ṣe ọdun mẹwaa si asiko yii la n lọ bayẹn.''

O ni ko le ju aarin ọdun mẹwaa yii lọ ti ẹni ti a n reti yoo fi de.

Wo igba mta ti Pasit Chris ni Jesus le pada de

Alufaa Oyakhilome ṣalaye fawọn ọmọ ijẹ rẹ pe akoko kan ninu mẹta ti oun la kalẹ ni Jesu yoo de.

''Yala ọdun meje siwaju tabi sẹyin tabi laarin, o le wa jẹ ọdun mẹtadinlogun ti Jesu yoo pada de; ọdun meje fun ipọnju ati ọdun mẹwaa ti alatako Kristi yoo fi dide,'' Pasitọ Chris lo ṣalaye bẹẹ.

O ni to ba jẹ pe ọdun meje siwaju ni, o tumọ si pe ọdun mẹta loku ti Jesu yoo fi de, ti o ba jẹ pe laarin in ni, ọdun mẹfa ati aabọ loku ti yoo fi de nitori oṣu mẹfa ti kọja ninu ọdun 2020, Pasitọ Chris ni o tumọ si pe ọdun mẹfa loku niyẹn ti Jesu yoo fi de.

Ni ede kukuru, Alufaa Oyakhilome sọ pe ti Jesu ko ba pada de lọdun mẹta si asiko yii, o le jẹ wi pe ọdun mẹfa ni yoo de, ti dide rẹ ko ba tun ya lọdun mẹfa, ko le ju ọdun mẹwaa lọ si asiko yii.

Ero awọn eeyan ṣọtọọtọ lori alaye ti Pasitọ Chris lori igba ti Jesu yoo pada de.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2

End of X post, 2

Skip X post, 3

End of X post, 3

Skip X post, 4

End of X post, 4

Skip X post, 5

End of X post, 5

Alufaa Oyakhilome ṣalaye siwaju sii pe awọn onimọ ijinlẹ naa mọ nipa akoko ti Jesu le de lo jẹ ki wọn maa gbero lati fun gbogbo eeyan to wa laye labẹ ajẹsara lọdun 2030 eyi ti wọn yoo fi ''chip'' si ara gbogbo eeyan.

''Ọdun 2030 lo wa lọkan ajọ GAVI ati MIT to n ri si ọrọ abẹrẹ ajẹsara, koda Eṣu gan an ti n gbiyanju lati mọ bibeli, bakan naa si lo n ti awọn eeyan tiẹ. Wọn ni afojusun wọn,'' Pasitọ Chris lo woye bẹẹ.