Rape: Olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ girama wọ gbaga ọlọ́pàá fẹ́sùn bíbá akẹ́kọ̀ọ́ lòpọ̀ ní ìlú Oyo

Ifipabanilopọ

Oríṣun àwòrán, Google

Mọlẹbi ọdọmọbinrin ọmọ ọdun mẹrinla kan ti pariwo sita lori ẹsun wi pe olukọ ile ẹkọ Federal Government Girls College ilu Oyo, fi tipatipa ba akẹkọọ naa sun.

Ẹgbọn ọmọdebinrin naa, Mercy Gabriel, nigba ti o ba awọn akọroyin sọrọ niluu ibadan lọjọ Ẹti ni iṣẹlẹ naa ti da aisan si ọmọ ọdun mẹrinla na lara.

Mercy ni nnkan to dun mọlẹbi oun julọ ni bi ọga agba ile ẹkọ naa ṣe kọ lati ṣe afihan olukọ ọhun fawọn ọmọ Naijiria, ki wọn le ri ẹni to ṣiṣẹ laabi naa.

"Aburo mi wale pẹlu awọn aburo rẹ sugbọn mo ri pe inu rẹ ko dun, mo beere lọwọ rẹ pe ki lo sẹlẹ sugbọn ko ba mi sọrọ."

Àkọlé fídíò, Amotekun Osun: Tí a kò bá ti kò ìbọn, kùmọ̀, àdá lọ ilé ìdìbò, ẹ má gbé 'yẹn wá o! Ojú l'alákàn fi ń ṣọ́rí

"Lẹyin oṣu kan ni ọkan lara awọn obi ti o jẹ ọrẹ mi, salaye fun mi bi olukọ kan, Alayoteti ṣe ba aburo mi sun."

"Ohun iyalẹnu lo jẹ fun mi nigba ti awọn obi mi lọ si ile ẹkọ naa, ti ọga agba fun ile ẹkọ naa ni irọ ni aburo mi pa lori iṣẹlẹ naa."

Sugbọn, awa mọlẹbi ṣe iwadii wa, lati wa olukọ naa, ti a si ri pe Arakunrin Timothy Alayoteti ti n ba aburo mi sun lati igba ti o ti wa ni ile ẹkọ girama kekere"

Ileeṣẹ ọlọpaa fidi iṣẹlẹ naa mulẹ:

Nígbà tí BBC Yorùbá kàn sí agbẹnusọ Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Olawale Osifeso, o fidii ọrọ naa mulẹ.

Osifeso ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa ati pe Timothy ti wa ni Ileeṣẹ ọlọpaa ni iyanganku.

O ni bi ọrọ naa ba ṣe n lọ, ni awọn yoo maa bun awọn ara ilu gbọ.

Aṣoju awọn ẹgbẹ obi ati olukọ ni ile ẹkọ naa, PTA, Arabinrin Nancy Faniran ni nigba ti ẹgbẹ naa da si ọrọ ọhun, ni ọwọ tẹ afurasi naa.

Faniran ni ohun iyalẹnu lo jẹ fun oun pe awọn alamojuto ile ẹkọ ọhun ko kọbi ara si iṣẹlẹ naa, ti ọga ile ẹkọ si ni iroyin ẹlẹjẹ ni iṣẹlẹ naa.

Agbẹnusọ Ileeṣẹ Olopaa ipinlẹ Oyo wa fi ọrọ sita pe iwadii bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa, ti awọn yoo si bu awọn ara ilu gbọ bi o ṣe lọ.