Láàrín oṣù méjé, ọmọ 80 lábí ní ibùdó àwọn ogúnléndé

Aworan ọmọde

Oríṣun àwòrán, Google

Ajọ pajawiri nipinlẹ Benue, SEMA ti kede pe awọn ti gbẹbi ọmọ ọgọrin laarin osu meje ti awọn ogun lende ti n gbe ni ipagọ to wa ni ipinlẹ naa.

Adari Ajọ SEMA,Emmanuel Shior lo fi lede ni Makurdi lasiko ti wọn n pin nkan iranwọ fun awọn eniyan.

Shior ni ajọ pajawiri naa lo ṣe akọsilẹ iye awọn ọmọ ti wọn n bi naa.

O ni pupọ ninu awọn ogunlende naa lo n gbe pẹlu awọn ololufẹ wọn, to si pẹlu bi awọn eniyan ṣe n bimọ ni ọwọọwọ.

‘’A kuku gbiyanju lati dena ibalopọ lọna aitọ ni ibugbe ogunlende ‘’

Aj̣ọ pajawiri SEMA naa ni gbogbo ọna ni awọn n gba lati ri pe awọn eniyan ko ma a ba ara wọn ni ibalopọ lọna aitọ ninu ọgba naa.

Amọ wọn ni ọ ṣoro lati dena ọmọ bibi ni ipagọ naa nitori eniyan naa ni awọn ofunlende naa.

‘’O ti wa ni ara eniyan lati ni ibalopọ bi wọn ko tilẹ ri ounjẹ jẹ.’’

‘’Bakan naa ni awọn ogunlende wọnyii wa pẹlu mọlẹbi wọn.’’

‘’Amọ ohun ti a tako ni ki awọn ayilọkọ ninu ọgba naa maa ba ara wọn ni ibalopọ, a tako o patapata.’’