"Ọkọ mi kò fi ilé ọmọ mi ṣe òògùn owó, ó ń yan ìṣẹ̀dá mi jẹ ni"
Obìnrin tó dáná sun ọkọ rẹ̀ ní èṣù ló gba ọwọ́ òun ṣiṣẹ́ torí ìyá ọkọ òun
Obinrin to dana sun ọkọ rẹ, Ifeoluwa, ti fi fọnran ohun kan silẹ, ko to ku eyi to si asọ loju eegun nipa idi to se pa ọkọ rẹ, Bolu Bamidele.
Fọnran ohun naa lo jẹ itakurọsọ to waye laarin Ife ati ọrẹ ọkọ rẹ kan ti a ko mọ orukọ rẹ, ẹni ti obinrin naa pe lori foonu.
Ninu fọnran ohun naa to din diẹ ni isẹju meji, ni Ife ti bu sẹkun pe ko yẹ ki ọkunrin naa, ọrẹ ọkọ rẹ ro pe oun ni oun pa ọkọ oun.
Mo nifẹ Bolu, n ko le pa amọ esu lo gba ọwọ mis sisẹ tori iya rẹ:
Ife lo n fi tomije tomije salaye pe oun nifẹ Bolu ọkọ oun, ti oun ko si le pa rara, o si yẹ ki wọn se iwadi iku to pa ọkunrin naa.
“N ko le pa Bolu, n ko si le se Bolu lese, iya rẹ lo fa ohun ti mo se:
Tori Bolu ni mo se di ẹni to n lọ si ṣọọṣi, no si sẹsẹ mọ pe Bolu ti ku ni, n ko mọ tẹlẹ.
Mi mọ pe ọkọ mi ti ku, mo ro pe ara rẹ maa ya, ti maa wa lọ ba, ti oun gan maa wa mọ pe esu lo gba ọwọ mi sisẹ.
Iya rẹ dẹ ni.”
Bolu, ẹni to n rọ ọrẹ ọkọ rẹ naa pe ko maa ka ohun ti oun n sọ lori foonu silẹ, ni ọkunrin naa wa n rọ pe ko ni suuru.
Awọn eeyan n parọ pe Bolu fi ile ọmọ mi se oogun owo:
Bakan naa ni Ifeoluwa sọ ninu fọnran ohun ti wọn ka silẹ ọhun pe awọn eeyan kan n sọ kiri pe Bolu ọkọ oun ti fi ile ọmọ oun se oogun owo, ni oun se pa.
Obinrin naa wa salaye pe ọkọ oun ko fi ile ọmọ oun se oogun owo nitori ko se oogun owo rara.
“Lootọ lo maa n yan isẹda mi jẹ amọ ẹ ma wulẹ pe mi mọ, mo ti gbe ohun ti mo fẹ gbe jẹ jẹ, lati akoko yii lọ, ohunkokohun si lo le sẹlẹ.
Obìnrin tó dáná sun ọkọ rẹ̀ mú májèlé láti pa ara rẹ̀ - Ọlọ́pàá
Ifeoluwa Bamidele, ti wọn lo dana sun ọkọ rẹ, Bamidele nilu Ibokun nipinlẹ Osun, ti jade laye.
Agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Yemisi Opalola lo fidi isẹlẹ naa mulẹ fun BBC Yoruba.
Nigba to n salaye bi obinrin naa se ku, Opalola ni irọlẹ Ọjọbọ ni Ife gbe ẹmi mi to si ki aye pe o digbose.
O ni irọ gbuu ni iroyin to jade saaju ọjọ naa obinrin naa pe o ti ku, o ni Ife sẹsẹ jade laye ni.
Obinrin naa n gbero lọwọ lati pa ara rẹ ni lasiko naa nitori ohun to kọ si oju opo Whatsapp rẹ.
Ijọ Katoliki fa Ife mọra lati yọju, ko ma gba ẹmi ara rẹ amọ...
Opalola ni ẹgbẹ kan to n wa alaafia ninu ijọ Katoliki, ẹka ti Ayepe nilu Osogbo ti wọn n pe ni Justice Development and Peace Makers Centre (JDPMC) kan si Ife lati fa a mọra.
Ọ ni ẹgbẹ naa gbe igbesẹ yii ko le rọrun lati tete ri Ife mu, ko maa ba gba ẹmi ara rẹ amọ o se ni laanu pe obinrin naa ku.
“Awọn agbẹjọro ẹgbẹ naa meji lo ni nọnba ipe obinrin naa, ti wọn si n rọ fa mọra pe ko mase pa ara rẹ.
Wọn ni ko wa gbe ara rẹ silẹ, ti wọn si sọ fun pe wọn yoo mu ki ọlọpaa din ẹsun rẹ ku, to si gba pe ki wọn fun mi ni nọmab oun.
Idi si ree ti mo fi pe lori aago, to si ba mi sọrọ.
Ife sọ pe oun kọ ni oun pa ọkọ oun – Alukoro ọlọpaa
Nigba to n salaye ijiroro rẹ lori foonu pẹu obinrin ti wọn lo pa ọkọ rẹ naa, Opalola ni obinrin naa sọ fun oun pe oun kọ ni oun pa ọkọ oun.
Alukoro ọlọpaa ni oun wa sọ fun pe oun gba bo se wi amọ ko maa sa kiri kọ ni yoo seranwọ fun, igba yẹn lo ni oun wa ni ilu Aramoko.
“Awọn agbẹjọro mejeeji to wa ninu ẹgbẹ JPDMC, ọkunrin kan ati obinrin kan, naa lo wa fi owo ọkọ ransẹ si Ife ni aramoko, pe ko maa bọ nile.
O ni oun ko ni owo kankan lọwọ mọ, a tiẹ fẹ fi owo to pọ ransẹ si amọ o ni rara, owo ọkọ nikan ni oun fẹ, ta si fi ransẹ si.
Gbogbo bo se n rin, lo n salaye fun wa, tori ọwọ aago mẹfa irọlẹ lo gba lati maa bọ si Osogbo lati aramoko.
O si ni oun ko ri ọkọ Osogbo taara mọ ni asiko yẹn, a sa ni ko maa bọ, ti awọn ikọ amofin naa si lọ gbe mọto lọ pade rẹ ni gareeji Ilesa.”
Ife ti mu majele ko to kuro ni Aramoko wa si Ilesa ti wọn ti gbe:
Alukoro fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Osun wa salaye fun BBC Yoruba pe bi Ife se de ọdọ awọn agbẹjọro to lọ pade rẹ ni gareeji, lo n se bii ẹnbi to fẹ bi.
O ni wọn bi pe ki lo n se, to si jẹwọ pe oun ti mu majele kan ti wọn n pe ni Sniper.
“Wọn gbe lọ sile iwosan to wa ni agbegbe naa nilu Ilesa, wọn si tiraka lati ri pe o pọ gbogbo majele to mu naa.
Amọ nitori pe o ti mu oogun asekupani naa tipẹ, ẹpa ko boro mọ fun Ife.
O si sọ fun wa pe oun ti mu majele naa, ko to di pe oun ba wa sọrọ ni irọlẹ, to si ti ba gbogbo inu rẹ jẹ, eyiun ko to di pe o de ọdọ wa.
Bi Ife se ku niyẹn, ti wọn si gbe oku rẹ wa si ile iwosan Katoliki to wa ni Osogbo lati se ayẹwo oku rẹ lati mọ oun to pa a.
Lẹyin eyi ni lo ni awọn yoo wa gbe oku rẹ fun awọn obi rẹ lati lọ sin, ti ẹjọ isekupani naa si pari sibẹ nitori Ife nikan ni afurasi ninu ẹjọ naa.

Oríṣun àwòrán, Ifeoluwa Bamidele
Ife kọ iwe silẹ ransẹ sawọn obi, ọrẹ ọkọ ati iya ọkọ rẹ, o ni oun n la aarẹ pọlọ kọja:
Opalola salaye pe awọn ọpọ iwe ti Ife ti kọ silẹ, ko to jade laye eyi to safihan rẹ pe obinrin naa ọpọlọ obinrin naa ko pe mọ.
“A ri ọpọlọ iwe ti Ife kọ silẹ fun awọn obi rẹ, ọrẹ ọkọ rẹ ati iya ọkọ rẹ, to si tun kọ iwe kan to gun pupọ eyi to fi salaye bi oun ati ọkọ rẹ se pade.
Bakan naa lo tun salaye ninu awọn iwe to kọ naa bi oun se n la isoro aarẹ ọpọlọ kọja.
O n mẹnuba ọrọ arun ọpọlọ pupọ ninu awọ̀n iwe to kọ silẹ, eyi to fihan pe o ni arun ọpọlọ.
Koda, o n beere ninu iwe yẹn pe se oun ni oun pa ọkọ oun ni? Oun kọ ni oun pa a. Se o ti ku ni?”
Opalola ni Ife tun salaye pe obinrin naa tun se alaye sinu akọsilẹ fọnran ohun ara rẹ to ka silẹ lori foonu rẹ.
Ọrẹ ọkọ rẹ to n ba sọrọ lo fi fọnran ohun naa ransẹ si nigba ti onitun ni ko maa bọ wa sile ni Osogbo.
Ninu fọnran ohun naa si ni Ife ti n sọ fun ọkunrin naa pe “O ti late”, gbogbo igba yẹn si lo ti mu majele.”
Ẹgbẹ ọkọ mi ni kẹ sin mi si, tori pe o sanwo ori mi – Ife Bamidele
Opalola ni awọn tun ri iwe kan ti Ife kọ silẹ, eyi to fi ni ki wn sin oun si ẹgbẹ ọkọ oun nitori pe ọmọkunrin naa sanwo ori oun.
















